Àwọn agbébọn kọlu baálè méjì l’Ogun, wọ́n pa ẹ̀ṣọ́ aláàbò kan

SP Ọmọlọla Odutọla, Alukoro ọlọpaa Ogun

Oríṣun àwòrán, NPF

Awọn agbebọn ti kọlu baalẹ meji nipinlẹ Ogun, wọn tun pa ẹṣọ alaabo So-Safe kan nibi to ti n gbiyanju lati ran awọn baalẹ naa lọwọ.

Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla ṣe fidi ẹ mulẹ, awọn baalẹ naa ni Saibu Razak lati Abule Keleu ati Sesi Odunjọ lati Abule Oko.

Gẹgẹ bi ẹka iroyin Punch ṣe wi, nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ọjọ naa ni ikọlu ọhun waye, lasiko tawọn baalẹ naa n bọ lati ibi ipade wọn labule Ọbalade, nipinlẹ Ogun.

Ìbọn ba àwọn baálẹ̀ lórí àti èjìká, ẹ̀ṣọ́ So-Safe kú

Aworan atẹ ipinlẹ Ogun

Oríṣun àwòrán, Others

O ṣoju mi koro kan ti ko darukọ rẹ, sọ pe ori ati ejika ni ibọn ti ba awọn baalẹ naa.

O ni lojiji lawọn agbebọn naa jade lati inu igbo. Wọn si bẹrẹ si i yinbọn.

Nibi ti wọn ti n yinbọn naa lo ti ba baalẹ kan lori to si ba ikeji lejika.

O fi kun un pe awọn So-Safe to debẹ lati koju wọn ni ọkan ninu wọn fara gba ọta to si ku.

A kò tí ì mú ẹnikẹ́ni lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ṣùgbọ́n ọwọ́ yóò padà tẹ̀ wọ́n- Alukoro ọlọpaa Ogun

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ lọjọ Aiku, ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹrin 2024, SP Ọmọlọla Odutọla, Alukoro ọlọpaa Ogun, sọ pe awọn ko ti i mu ẹnikẹni lori iṣẹlẹ naa.

O ni ṣugbọn o daju pe ọwọ yoo ba awọn to ṣe ikọlu ọhun, wọn yoo si jẹjọ labẹ ofin bo ṣe yẹ.

Ṣaaju ni Odutọla ti kọkọ sọ ninu atẹjade to fi sita, pe ẹṣọ alaabo to ku naa pẹlu awọn meji mi-in ni wọn koju awọn agbebọn yii.

O ni wọn ko si fi bẹẹ ni nnkan ija lọwọ.

Alukoro sọ pe bi ibọn ṣe ba oloogbe naa ni wọn gbe e lọ sileewosan, ṣugbọn o papoda ki dokita too yẹ ẹ wo rara.