Nǹkan tí ó le mú ọ̀wọ́ngógó oúnjẹ dínkù ní Nàìjíríà rèé - Ẹgbẹ́ àgbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yoruba bọ wọn ni ebi kii wọnu ki ọrọ mii wọ ọ.
Ọrọ ọwọn gogo to gbode ni orilẹ ede Naijiria kan ara ile kan ara oko
Eyi lo mu awọn agbẹ ni ẹkun iwọ-oorun ni orilẹ ede yii ṣe gbe ipade apero kan ide lati wa ojutuu sọrọ ebi to gbode kan lasiko yii.
Nigba to n sọrọ nibi ipade naa, alaga ẹgbẹ awọn agbẹ ni agbegbe iwọ-oorun Naijiria, Ọmọba, Segun Dasaolu rọ gbogbo awọn agbẹ lati pada si oko, ki ipese ounjẹ le pọ yanturu.
O ni ti ebi ba ti kuro ninu iṣẹ, iṣẹ buṣe ati pe bi Naijiria ko ṣe maa pese ounjẹ to to ṣe amulo fun awọn eniyan rẹ lo fa bi ounjẹ ṣe n gbowo lori ni gbogbo igba.
Dasaolu ni loootọ ni pe ọrọ aabo lo le ọpọ agbẹ kuro loko amọ to woye pe eto aabo Naijiria ti gbopọn si ju ti tẹlẹ lọ.


O rọ wọn lati ma bẹru lati pada si oko, pe aisi eto aabo ni Naijiria ti n lọ si okun igbagbe.
O fi kun ọrọ rẹ pe awọn agbẹ ni agbegbe iwọ-oorun Naijiria ti ṣetan lati mu ọrọ aisi ounjẹ kuro ni orilẹ ede yii, pe awọn ti ṣetan lati ri daju pe a n pese ounjẹ to maa to ṣẹku fawọn eeyan Naijiria.
O ni "a gbọdọ mọ awọn ti wọn n ṣe iṣẹ agbẹ ni ipinlẹ kọọkan, ki akọọlẹ fun gbogbo awọn to n ṣiṣẹ agbẹ ni Naijiria ki a le jẹ anfani ijọba bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.”
Alaga naa fi kun pe oun ranṣẹ si minisita fun ọrọ agbẹ lati maa ṣe abẹwo si awọn igberiko ki wọn le mọ bi ibi ti iṣẹ agbẹ de duro ni orilẹ ede yii.
Dasaolu ni ṣiṣe eyi ni yoo fun minisita naa ni anfani lati mọ awọn ohun to n jẹ awọn agbẹ niya kaakiri agbegbe wọn ati pe wọn yoo mọ ọna to tọ lati wa atunṣe si gbogbo awọn iṣoro naa.

Lara ohun to waye nibi apero naa ni bi ẹgbẹ agbẹ ati ẹgbẹ awọn darandaran, Myetti Allah ṣe tọwọbọ adehun alafia laaarin awọn mejeeji pe awọn maa ri daju pe ko si ogun tabi ọtẹ laaarin awọn eyi to le ṣakoba fun aabo pipese ounjẹ.
Iyalọja gbogbo gbo ni orilẹ ede Naijiria, Folashade Tinubu-Ojo ti oun naa bawọn peju sibi apero naa tẹnumọ pe titọwọ bọ iwe adehun alafia ti ẹya mejeeji yii buwọlu yoo pọnkun ọrọ eto aabo ni orilẹ ede Naijiria.















