Chris Oyakhilome: Pásítọ̀ Nàíjíríà tó n bu ẹnu àtẹ́ lu abẹ́rẹ́ àjẹsára tó n dèna àìsàn ibá

Aworan Pasito Chris

Oríṣun àwòrán, Pastor Chris Online

Odu ni Pasitọ Chris Ọyakhilomẹ, alaṣẹ ati oludari ijọba Christ Embassy kaakiri agbaye, kii ṣaimọ f’oloko lorileede Naijiria, ati kaakiri agbaye.

Lara awọn ohun ti aye fi mọ Oyakhilome ni awọn iṣẹ iyanu to maa n ṣe ninu ijọ rẹ, ati awọn ibi ipade ita gbangba to maa n ṣe.

Ọyakhilome wa lara awọn pasitọ ti ko gbagbọ ninu lilo oogun oyinbo tabi ti ibilẹ, ṣugbọn to gbagbọ daadaa ninu iṣẹ iyanu ati iwosan atokewa, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni ‘Miracle and Divine Healing’.

Lati bi oṣu meloo sẹyin ni Pasitọ Oyakhilome ti bẹrẹ sii polongo ninu ijọ rẹ, ati lori ikanni ayelujara wi pe oun ko nigbagbọ ninu abẹrẹ ajẹsara to n dena aisan iba, iyẹn ‘Malarial Vaccines’ ti wọn n gbe kaakiri.

Pasitọ Oyakhilome ni “ko tii si aridaju kankan wi pe abẹrẹ ajẹsara naa ti ṣiṣẹ fẹnikẹni.”

Nibi iwaasu rẹ to ṣe ninu oṣu keji, ọdun yii, eyi to wa lori ikanni YouTube ijọ rẹ, o ni “irọ ni wọn ti n pa fun gbogbo eeyan”

Ninu iwadii BBC si awọn iwaasu rẹ laarin ọdun 2023 si 2024 ni Oyakhilome ti n tako awọn abẹrẹ ajẹsara naa, paapaa awọn eyi ti wọn n pin si ilẹ Afrika kaakiri.

Bi ẹ ko ba gbagbe, ọkan pataki lara awọn aisan aṣekupani ni aisan iba jẹ nilẹ Afrika. Ida marundinlọgọrun awọn eeyan lo ti ku kaakiri agbaye lori aisan iba lọdun 2022.

Ida ọgọrin ninu awọn to ku yii lo jẹ ọmọde ti wọn ko tii pe ọdun marun-un, gẹgẹ bi ajọ eleto ilera agbaye, World Health Organization (WHO) ṣe sọ.

Aworan omo to n gba abere ajesara

Oríṣun àwòrán, Reuters

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati bii oṣu mẹfa sẹyin, Pasitọ Oyakhilome ti gbe oriṣiriṣi fọnran oni-ogun iṣẹju jade sori awọn ikanni ayelujara kaakiri lati fi tako awọn abẹrẹ ajẹsara, ti wọn si lo tun ṣafihan rẹ lasiko iwaasu fun awọn ọmọ ijọ rẹ.

Ikede ti wọn gbe jade lọdun to kọja nipa awọn abẹrẹ ajẹsara yii, lẹyin ọpọlọpọ ọdun sẹyin ti wọn ti n gbiyanju, ni awọn onimọ ti n gbe oṣuba kare fun, ti wọn si ni aṣeyọri nla ti yoo daabo bo ẹmi ẹgbẹẹgbẹrun eeyan kaakiri agbaye.

Gẹgẹ bi ajọ iṣọkan agbaye to n ri sọrọ awọn ọmọde, UNICEF ṣe sọ, wọn ni latigba ti wọn bẹrẹ ipolongo abẹrẹ ajẹsara lọdun 2019 lawọn orileede bii Kenya, Ghana ati Malawi ti mu adinku ba iku awọn ọmọde ni ida mẹtala.

Ṣugbọn ṣa, ibẹru nla lo n jẹ fawọn onimọ wi pe bi gbajugbaja pasitọ yii ṣe n waasu, to si n polongo lati tako awọn abẹrẹ ajẹsara naa le ṣakoba fun pinpin wọn sawọn ilẹ Afrika.

Ninu oṣu kẹjọ, ọdun to kọja, o se ikilọ ninu iwaasu rẹ to pe ni “ipinnu buruku to ti wa nilẹ lọjọ to ti pẹ (an evil agenda that has been long in the making)”.

Bakan naa lo tun jẹ ko di mimọ pe ọna lati din awọn eeyan ku lagbaye ni erongba abẹrẹ ajẹsara naa jẹ.

Bẹẹ lo sọ pe “aisan iba kii ṣe iṣoro f’awọn ẹya ilẹ Afrika.”

“Gbigbe ayederu iroyin nipa abẹrẹ ajẹsara, paapaa lati ọdọ awọn ilu mọ-ọn ka bawọnyi le da ariyanjiyan nla silẹ, ko si ṣakoba fun itankalẹ pinpin abẹrẹ ajẹsara naa.

“Eyi tun le ni atubọtan ti ko dara nipa eto ilera, paapaa ni awọn ilẹ Afrika ti ajọ WHO ti n tiraka lati dena aisan ati ajakalẹ arun,” agbẹnusọ ajọ WHO.

Awọn ọrọ Oyakhilome wa ninu awọn ti wọn fi n bu ẹnu atẹ lu abẹrẹ ajẹsara ninu iwadii ti wọn gbe jade ninu oṣu kẹta lati ọdọ awọn alatilẹyin WHO, iyẹn The Africa Infodemic Response Alliance.

“A ti beere fun awọn ọrọ pasitọ naa nipa abẹrẹ ajẹsara lori imeeli ileeṣẹ ati ti ṣọọṣi rẹ, ṣugbọn a ko gbọ ohunkohun.”

Aarin ọdun 1990s ni pasitọ yii da ijọ Christ Embassy rẹ lorileede Naijiria, iyẹ niluu Eko, to si lọ lati ni awọn ọmọ ijọ kaakiri agbaye.

Lọdun 2011, wọn gbe e soju iwe iroyin magasiini nni, Forbes gẹgẹ bi ọkan lara awọn pasitọ to lowo julọ lorileede Naijiria, pẹlu iye owo to to ọgbọn miliọnu si aadọta miliọnu owo dọla ($30m).

Gẹgẹ bi magasiini naa ṣe kọ ọ, lara awọn iṣẹ okoowo ti gbajugbaja pasitọ naa tun n ṣe ni iwe iroyin, magasiini, tẹlifiṣan, ileeṣẹ to n gbe orin jade, itakun amohunmaworan, otẹẹli ati gbagede ti wọn ti n ta ile ati ilẹ (extensive real estate).

Ileeṣẹ rẹ to pe ni LoveWorld Inc, ti dagba gidi. Lara awọn to si fi n ṣe ni gbigbe fọnran jade, ati ikanni ibara-ẹni sọrọ ti ọpọ awọn eeyan n lo loorekoore ati banki ẹyawo ti a mọ si microfinance bank.

Ni ẹẹkan laarin ọsẹ, Oyakhilome maa n waasu ni ilẹ ipagọ ṣọọṣi rẹ to wa lagbegbe Aṣeṣe, opopona marosẹ Eko si Ibadan.

Nigba ti BBC lọ si ijọ rẹ ninu oṣu kọkanla, ọdun to kọja, ogunlọgọ awọn pasitọ lati ile ijọsin miran kaakiri lo wa nibẹ lati kopa nibi ipagọ awọn iranṣẹ Ọlọrun ọlọdọọdun ti wọn maa n ṣe.

Asia ọpọlọpọ orileede ni wọn gbe kọ soke ninu ile ijọsin naa.

Iwaasu rẹ ati awọn iṣẹ iyanu rẹ ni ọpọ awọn eeyan kaakiri agbaye to le ni biliọnu meje wo, gẹgẹ bi ikanni ayelujara Christ Embassy ṣe sọ.

Winnifred Ikhianosin, ẹni ọdun marundinlọgbọn toun naa maa n lọ si ṣọọṣi rẹ, ẹni to ba BBC sọrọ ṣalaye pe oun kii gba abẹrẹ ajẹsara

“Ojiṣẹ Ọlọrun yii lo sọ fun wa, ẹmi naa si ṣe awọn iwadii mi.”

Gẹgẹ bi Ada Umenwaliri, ọkan lara awọn alakoso ni African Studies Centre to wa ni fasiti kan nilẹ Amẹrika ti North Carolina ṣe sọ, o ni gbogbo awọn ololufẹ rẹ ni wọn maa n gba ọrọ Pasitọ Oyakhilome gbọ.

Ninu apilẹkọ kan ti ileeṣẹ iroyin ori ayelujara The Cable gbe jade lọdun to kọja, ẹni to kọ apilẹkọ naa, Julius Ogunro sọ nibẹ pe awọn ohun ti Oyakhilome n sọ lewu pupọ, ko si ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ẹsin Kristiẹni.

Ogunro, to tẹnumọ Bill Gates gẹgẹ bi ẹni to n ṣe iranwọ lori itankalẹ abẹrẹ ajẹsara naa tun ti yi ipinu rẹ pada lori bi Oyakhilome ṣe n bu ẹnu atẹ lu.