Ọ̀rọ̀ epo pupa dá wáhàlá láàrin ìyá àti ọmọ rẹ̀ l'Osun, ẹ̀mí ìyá bọ́ síi

Galagala lọwọ

Oríṣun àwòrán, Daily Post

Niṣe ni ọrọ di ẹfun abi eedi ni ilu Kajola, Apomu Ikire, ijọba ibilẹ Isokan, ipinlẹ Osun nigba ti iroyin gbode pe ọkunrin kan pa iya rẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ ni pe ọrọ owo epo pupa lo da awuyewuye silẹ laaarin iya ati ọmọ naa ko to di pe ọmọ naa ti iya rẹ ti iya naa si gba ibẹ jẹ Ọlọrun nipe.

Afurasi naa Luku Odejoju, ẹni ọdun mẹtalelọgọta ti wa ni ahamọ awọn ọlọpaa.

Nigba to fi idi iṣẹlẹ naa fun BBC News Yoruba, agbenusọ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ ohun to ṣokunfa aawọ naa.

Opalola ni ọjọ Kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ni nnkan bii aago mẹwaa owurọ ni arakunrin kan ti orúkọ rẹ ń jẹ Rabiu Odejoju ti o gbe ni oko kan ti wọn pe orúkọ rẹ ni Kajola ni Apomu Ikire lọ fẹjọ sun ni agọ ọlọpaa.

Rabiu Odejoju lo wa si agọ ọlọpaa to wa ni Apomu Ikire to si salaye iṣẹlẹ laabi ọhun wi pe afurasi Luku Odejoju tii iya rẹ ọmọ ọgọ́rùn-ún ọdun lulẹ ti iya naa si gbe ẹmi mi.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa ṣalaye wi pe ohun to fa Isẹlẹ naa ni bi afurasi Luku Odejoju se tii iya rẹ Aminat Yusuf Odejoju lulẹ nitori ọrọ epo pupa.

O tẹsiwaju wi pe afurasi naa nigba ti awọn n gba ọrọ énu rẹ kalẹ ni oun ko ṣa deede ti iya naa ṣubu nitori epo pupa, sugbọn ọrọ awọn ko ye ara awọn bi oun ṣe n ṣalaye fun mọmọ oun bi ọrọ epo pupa naa se jẹ.

“Ṣugbọn lojiji ni ọwọ mi ṣa deede gba mọmọ lẹgbẹ ti iya naa si ṣubu lulẹ lojiji to si gbe ẹmi mi,” afurasi naa sọ fun awọn ọlọpaa.

Opalola ni oku iya naa ti wa ni ipamọ bayii

Bakan naa lo ni iwadi ọrọ naa n tẹsiwaju ati wi pe afurasi naa, Luku Odejoju ti wa ni kolo awọn ọlọpaa bayi fun iwadii to peye.