Òjò àrọ̀rọ̀dá bẹ́ sílẹ̀ ní Pakistan, omi gbé ọ̀pọ̀ lọ, àrá sán pa èèyàn 21

Pakistan Flooding

Oríṣun àwòrán, EPA

O kere tan, eeyan mọkandinlogoji lo ti jade laye ni Pakistan bayii lẹyin ojo to rọ fun ọjọ gbọọrọ lagbegbe ariwa iwọ oorun orilẹede naa.

Awọn alaṣẹ ni lara awọn to ku ni awọn agbẹ ti ara san pa lasiko ti wọn n ko ere oko wọn.

Aworan ori ayelujara ṣafihan awọn oko ti ojo ti wọ lọ, ojo naa si ti ṣakoba fun ina mọnamọna.

Pakistan wa lara awọn orilẹede ti oju ọjọ rẹ n ṣe segesege latari ayipada oju ọjọ.

Lọdun 2022, ida mẹta orilẹede naa ni omi ya bo, ninu eyii ti ẹmi eeyan 1,700 ba lọ ti ọpọ tun farapa.

Nibi iṣẹlẹ ọhun ni ọpọ miliọnu eeyan ti di alairilegbe, ti ẹgbẹlẹgbẹ ko si ri omi to mọ geere mu.

Lara awọn agbegbe to fara gba ninu iṣẹlẹ naa lọdun 2022 ni Khyber Pakhtunkhwa ati Balochistan, iṣẹlẹ to tun waye lọdun yii tun kan awọn agbegbe yii kan naa.

Ajọ to n bojuto iṣẹlẹ pajawiri nilẹ naa, National Disaster Management Authority, ti sọ pe ki awọn araalu maa mura iṣẹlẹ ilẹ riri mii ati iṣẹlẹ omiyale lakọtun.

Lara awọn agbegbe ti eeyan ti ku julọ ni Punjab, to jẹ ibi ti eeyan pọ si ju lorilẹede ọhun.

Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe eeyan mọkanlelogun ni ara san pa ni Punjab yii laarin ọjọ Ẹti si ọjọ Aje to kọja.

Yatọ si Pakistan, iṣẹlẹ omiyale tun kọlu Afganistan to fẹgbẹkẹgbẹ rẹ, nibi ti eeyan mọkanlelọgbọn ti dagbere faye lọjọ Aiku.