Mo máa kó padà sí Nàìjíríà láti gbé àṣà àti ìrìnàjò wa ga- Pelumi Nubi

Àkọlé fídíò, Mo rò pé ìrìnàjò mi parí lẹ́yìn tí mo ní ìjàmbá ọkọ̀ - Pelumi Nubi
    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọdọmọbinrin to wa mọto lati ilu London wa si ilu Eko, Pelumi Nubi ni igbagbọ oun ni pe irinajo oun ti wa sopin lẹyin to lugbadi ijamba ọkọ, eyi to sọ dero ile iwosan.

Nubi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ba BBC Yoruba sọrọ lori awọn ipenija to lakọja lasiko irinajo rẹ ati awọn igbaradi to ṣe saaju ko gunle irinajo naa.

O ni wọn bi oun si ipinlẹ Eko sugbọn awọn obi oun mejeeji wa lati ipinlẹ Ogun.

Aworan Pelumi Nubi

“Lati ọmọ ọdun mẹwaa ni mo ti lọ si ilu, to si jẹ pe ibẹ ni mo n gbe bayii.”

Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹta ni iroyin jade pe ori yọ Nubi ninu ijamba ọkọ ni orilẹede kan ni Afrika.

Nigba to n sọrọ nipa ijamba naa, o ni gbogbo erongba oun nipe opin ti de ba irinajo ti oun gunle nitori ninu ẹru ni oun wa.

“Ijamba ọkọ naa bami lẹru gan-an nitori mo wa ni ibi ti n ko mọ ede wọn, ede faranse ni wọn sọ nibẹ.

“Mo ro pe irinajo naa ti tan nitori mọto naa bajẹ pupọ.”

Ọrọ pọ lẹnu Pelumi Nubi, ẹ wo fọnran yii