Wo ọkùnrin kan tó gbẹ́ kànga bíi ọgọ́rùn ún láti ṣe ìrànwọ́ fáwọn èèyàn ìgbèríko ní Senegal

Ọkunrin kan, Junior Diakhaté to jẹ oniṣẹ iran-ara-ẹni ti gbẹ kanga
bi ọgọrun un fawọn eeyan to n gbe igberiko lorilẹede Senegal lati bawọn wa ojutuu si iṣoro omi ti wọn n koju.
O ni idunnu ati iwuri lo jẹ fun un, ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ ayo oun ni pe erongba oun wa si imuṣẹ.
Ọpọ igberiko Senegal ni ko ni omi to dara fun mimu.
Ọgbẹni Junior ti fi ọdun kan sẹyin ko owo jọ eyi to fi n gbẹ kanga kaakiri awọn abule ti wọn ko ti ni omi to dara fun mimu.
Olugbe abule kan, Adam Ba sọ pe ''a le rin lọ si odo lati lọ pọ omi ni igba mẹjọ lojumọ.
A maa n lọ pọ omi nigba mẹrin laarọ ati nigba mẹrin ni irọle.
Inu wa maa n dun bi ẹni to n lọ si paradise ni.
Anfani nla lo jẹ fun wa.''
Iṣẹ ti Junior n ṣe ti ṣakoba fun ẹbi rẹ.
Koda, ko si nibi isọmọlorukọ ọmọbinrin rẹ to waye laipẹ.
Amọ, Junior ti pinu lati tẹsiwaju pẹlu iṣẹ rẹ.
''Koda, to ba jẹ wi pe ma a ku sọna, amọ, mi o gbadura iru rẹ, tabi ku sibi ti a ti n ṣiṣẹ, o maa tẹmi lọrun.
Tori ihuwasi awọn eeyan maa n fun mi ni iwuri.
Kanga gbigbẹ ti funmi layọ lọpọlọpọ,'' Junior lo sọ bẹẹ






