Osolo ìlú Isolo papòdà lẹ́yìn àdúrà Yidi lọ́jọ́ ọdún ìtúnu ààwẹ̀, Sanwo-Olu kẹ́dùn Ọba Agbabiaka

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu/X
Ọba Kabiru Agbabiaka, Osolo ti ilu Isolo to jẹ kabiyesi ni ijọba ibilẹ Isolo ni ipinlẹ Eko ti jade laye.
Ọba Agbabiaka ni a gbọ pe o jade laye lẹyin adura itunu aawẹ ni Ọjọru niluu Eko.
Alaga ijọba ibilẹ Isolo, Họnọrebu Olasoju Adebayo lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade kan to fi sita.
Ẹni ọdun mẹrinlelọgọta ni Kabiyesi Agbabiaka i ṣe ki o to jade laye.
‘’Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko sọ fun mi pe ki n kede ipapoda Ọba Isolo, Kabiyesi Kabiru Alani Adelaja Agbabiaka, Adeola Olushi Kẹta lọjọ kẹwaa oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii,’’ alaga ijọba ibilẹ Isolo lo sọ bẹẹ.
Gomina Babajide Sanwo-Olu kẹdun Osolo to papoda
Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu n ṣedaro Ọba Agbabiaka to waja lọjọ ọdun itunu aawẹ.
Sanwo-Olu sọ pe ''pẹlu ibanujẹ ọkan ni mo fi gba iroyin ipapoda Osolo ti ilu Isolo.
Ọba Osolo to waja jẹ ọba alaye ti ki i ṣe aladanikanjọpọn ti o ṣi fi aye rẹ sin ilu Isolo ati ipinlẹ Eko titi ti ọlọjọ fi de.
Ọba Agbabiaka ti fi ipa rere lelẹ eyi tawọn eeyan ko le gbagbe laelae.
Mo kẹdun pẹlu awọn ẹbi, ọrẹ ati awọn eeyan Isolo lori ipapoda Ọba Agbabiaka.
KI Eledua tẹ ẹ si afẹfẹ rere, ki orukọ rere ti o fi silẹ ma bajẹ laelae.''
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post














