Adẹ́rìnínpòṣónú AY sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn tó lu orí ayélujára pa nípa ìgbéyàwó rẹ̀

Aworan AY ayi iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, AY Comedian/Instagram

Gbajugbaja adẹrininpoṣonu n ni, Ayo Makun ti ọpọ eeyan mọ si AY ti sọrọ lori iroyin to tan ka ori ayelujara pe igbeyawo rẹ to ti pe ogun ọdun bayii ti fori ṣanpọn.

AY sọrọ lẹyin ahesọ ọrọ kan pe o ni ibalopọ pẹlu oludije eto BBNaija kan tẹlẹ ri.

Ninu ọrọ ti o fi lede loju opo Instagram rẹ, AY ni kawọn kan ma lọ rope ti eeyan ba dakẹ nigba mii, ko tumọ si pe ẹni naa ko lagbara.

Amọ, o gba ninu ọrọ rẹ pe oun ti ṣe awọn nnkan kan ti ko wu oun gan an lori.

‘’Ọpọ eeyan lo maa n ro pe ti eeyan ba dakẹ tumọ si pe ẹni naa ko lagbara lati wa ojutu si ipenija to n koju rẹ.

Ti awọn eeyan ba si n gbe oriṣiiriṣii ahesọ ọrọ kiri nipa ẹnikan, ko tumọ si pe ẹni naa ko le gbija ara rẹ.

Awa eeyan kan kan mọ pe iyatọ wa laarin erongba eeyan, igbagbọ, aṣa ati ohun to jẹ otitọ.

Abuda ati irisi mi ti fidi rẹ mulẹ pe mo ti de ipele ti n ko le maa sọ gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ninu ẹbi mi sita papaa julọ lori ayelujara.

Kii tiẹ wa ṣe igba ti mo ti ni ọmọbinrin to ti dagba bayii ti oun naa ṣi wa lori ayelujara.

Mo ni lati daabo bo o ki awọn ohun to n ri lori ayelujara ma ba ṣakoba fun ilera rẹ.

Aworan AY ayi iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, AY Comedian/Facebook

Lootọọ ni mo ti ṣe awọn nnkan kan ti ko jẹ nnkan iwuri fun emi gan an fun ra mi.

Otitọ ni pe igbeyawo mi to ti pe ogun ọdun n daru lọ, amọ, o tun ṣe pataki fun gbogbo ẹni ti ọrọ naa kan lati ṣọra ṣe, ki wọn si mọ ẹni ti wọn maa dẹbi ru lori opo ayelujara tawọn obinrin ti n saba maa jare.

Mo le fi gbogbo ẹnu sọ pe ko si ẹni ti ki i ṣe ole ti ile ba da.

Ni bayii, mo fẹran bi oriṣiiriṣii awọn akọroyin ori ayelujara ti n pa irọ mọ mi.

Amọ, o dami loju pe otitọ ni yoo bori gbogbo irọ ti wọn n pa mọ mi,’’ AY ṣalaye.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post