Ilé aṣòfin yọ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Edo Philip Shaibu nípò lẹ́yìn ọ̀pọ̀ èdè-àì-yedè pẹ̀lú Obaseki

Aworan Godwin Obaseki ati Philip Shaibu

Oríṣun àwòrán, Philip Shaibu/X

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo ti yọ igbakeji gomina ipinlẹ naa, Philip Shaibu nipo lẹyin ọpọlọpọ gbọmisi-omi-o-to to ti waye laarin rẹ ati gomina Godwin Obaseki.

Lonii ọjọ Aje ọjọ kẹjọ oṣu Kẹrin ọdun 2024 ni ile yọ Shaibu nipo eyi to jẹ igbesẹ ti wọn fi pari ohun ti wọn ti bẹrẹ lati bi oṣu meloo kan sẹyin.

Iyọnipo Shaibu da lori gbigba wọle abọ igbimọ ẹlẹni meje kan ti adajọ agba ipinlẹ Edo, Adajọ Daniel Okungbowa ṣe ifilọlẹ rẹ lori ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan Shaibu.

Lasiko ijokoo ile lonii, adari ẹgbẹ oṣelu to pọ julọ, Charity Aiguobarueghian, sọ pe abọ igbimọ ẹlẹni meje to ṣiṣẹ lori iyọnipo naa ni koko meji ninu.

Aiguobarueghian ṣalaye pe igbimọ naa ko le fidi ẹsun jijẹri eke ti wọn fi kan Shaibu mulẹ, amọ, igbimọ ọhun fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun sisọ aṣiri ijọba sita.

Ninu abọ igbimọ yii ni wọn ti gba ile ni imọran lati yọ igbakeji gomina nipo latari pe o n sọ aṣiri ijọba sita.

Akọwe ile, Yahaya Omogbai ka gbogbo awọn ọmọ ile to dibo yala fun aba lati yọ ọ nipo tabi tako aba naa.

Mejidinlogun ninu mọkandinlogun ọmọ ile lo gba aba lati yọ Shaibu wọle, nigba ti ẹyọkan yooku kọ lati dibo.

Akọwe ile sọ pe ida meji ninu mẹta ọmọ ile lo gbọdọ fọwọ si iyọnipo igbakeji gomina ki o to le ṣeeṣe.

Ẹwẹ, adari ile aṣofin ipinlẹ Edo, Blessing Agbebaku, ti sọ fun Omogbai lati fi ẹda iwe iyọnipo naa ransẹ si Gomina Obaseki fun ibuwọlu.

Iyọnipo yii waye lasiko ti ile ẹjọ giga niluu Abuja fẹ bẹrẹ ẹjọ ti Shaibu pe lati tako igbesẹ ile aṣofin Edo lati yọ ọ nipo.