Ìjọba àpapọ̀ kéde Ọjọ́bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àfikún ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ fún ọdún ìtúnu ààwẹ̀

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/ASIWAJU BOLA AHMED TINUBU
Ijọba apapọ ti kede Ọjọbọ tii ṣe ọjọ kọkanla oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii gẹgẹ bi afikun ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ fun ọdun itunu aawẹ.
Ọrọ yii jẹyọ ninu atẹjade kan ti akọwe agba ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ abẹle, Ọmọwe Aishetu Nadayako fi lede loju ọpo X rẹ lonii ọjọ Iṣẹgun.
‘’Ijọba apapọ ti kede Ọjọbọ gẹgẹ bi afikun ọjọ isinmi fun ayẹyẹ ọdun itunu aawẹ.
Minisita ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ abẹle, Ọmọwe Olubunmi Ojo nigba to n ki awọn musulumi ku ọdun, fidi rẹ mulẹ pe Aarẹ Bola Tinubu ko ni kaaarẹ ninu akitiyan rẹ lati sọ orilẹede Naijiria di ibi to rọrun fawọn araalu lati gbe ati lati rowo ṣe aye,’’ ‘Ọmọwe Ndayako lo sọ bẹẹ.
Ni ọjọ Aje ni ijọba Saudi Arabia kede pe awọn ko riu oṣu tuntun eyi to tumọ si pe awọn musulumi yoo tun gba aawẹ lonii ọjọ Iṣẹgun nigba ti ọdun itunu aawẹ yoo si waye ni Ọjọru.
Ṣaaju ni ijọba orilẹede Naijiria ti kede ọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru gẹgẹ bi ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ fun ayẹyẹ ọdun itunu aawẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ìtunu-ààwẹ̀: Ìjọba àpapọ̀ kéde ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́rú bí ìsinmi lẹ́nuu iṣẹ́

Oríṣun àwòrán, BBC/Olubunmi Tunji-Ojo@ X
Ijọba apapọ Naijiria ti kede ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an ati Ọjọru, ọjọ kẹwaa oṣu kẹrin 2024 gẹgẹ bii ọjọ isinmi lẹnu iṣẹ, lati sami ọdun Itunu-aawẹ.
Minisita fun Ọrọ abẹle, Olubunmi Tunji Ojo lo sọ eyi di mimọ loju opo X rẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanla, oṣu kẹta ọdun 2024 yii ni aawẹ Ramadan ọdun yii bẹrẹ, to si ṣee ṣe ko pari lọjọ kẹjọ oṣu kẹrin.
Bi wọn ko ba ri oṣu Shawwal to n tọka ipari aawẹ lọjọ kẹjọ, wọn yoo pari rẹ lọjọ Iṣẹgun ti i ṣe ọjọ kẹsan-an oṣu kẹrin, 2024.
Sultan Sokoto ní káwọn Musulumi bẹ̀rẹ̀ sí í wá oṣù Shawwal láti ọjọ́ Ajé

Oríṣun àwòrán, Sultan's Palace
Igbimọ to n ri si wiwa oṣu tuntun lati Aafin Sultan ilu Sokoto, Alhaaji Muhammad Sa'ad Abubakar kẹta, ti ni kawọn Musulumi bẹrẹ si i wa oṣu tuntun Shawwal, bẹrẹ
lati ọjọ Aje ọsẹ yii, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin ọdun 2024.
Oṣu tuntun naa ni Shawwal ọdun 1445 ninu onka ọdun awọn ẹlẹsin Islam.
Ìpè yii waye ninu atẹjade kan to wa lati ọdọ igbimọ to n wa oṣu tuntun naa.
‘’Ki ẹnikẹni to ba ri oṣu Shawwal fi to olori agbegbe rẹ leti, oun ni yoo sọ fun Sultan ti yoo fi kede’’
Bakan naa ni aafin Sultan Sokoto ti pese awọn nọmba ẹrọ ibanisọrọ tawọn eeyan le pe si, bi wọn ba ri oṣu tuntun naa.
Riri oṣu Shawwal lo n kede opin aawẹ Ramadan fawọn Musulumi, lẹyin rẹ ni wọn yoo ṣọdun Itunu-aawẹ.
Ṣugbọn bi wọn ko ba ri oṣu tuntun naa lẹyin ti Ramadan ti pe mọkandinlọgbọn, wọn yoo gba aawẹ kan si i lati pe ọgbọn ọjọ.
Ọjọ keji ni yoo si jẹ ọjọ akọkọ oṣu Shawwal ti wọn yoo ṣọdun Itunu-aawẹ













