Sanwo-Olu fi ẹ̀bùn ilé, ọkọ̀ àti ipò dá Pelumi tó wa ọkọ̀ láti London sí ìlú Eko lọ́lá

Oríṣun àwòrán, Jubril A. Gawat/X
Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko ti fi ẹbun ọkọ, ile ati ipo aṣoju ipinlẹ naa da Pelumi Nubi to wa ọkọ lati ilu London lorilẹede Uk wa si Naijiria lọla fun aṣeyọri rẹ.
Nigba ti o gba Pelumi ni alejo lọjọ Aje ọjọ kẹjọ oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii ni gomina Sanwo-Olu kede awọn ẹbun yii.
Ọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu kẹrin yii ni Pelumi gunlẹ si ilu Eko lẹyin to ti wa ọkọ kọja ni orilẹede mẹtadinlogun lati UK de Naijiria.
Tijo-tilu lawọn ololufẹ rẹ fi pade Pelumi nile ẹkọ giga fasiti UNILAG lọjọ Aiku.
Oludamọran si gomina lori ọrọ iroyin, Gboyega Akosile ṣalaye loju opo X rẹ pe Sanwo-Olu ti yan Pelumi sipo gẹgẹ aṣoju ipinlẹ Eko lori ọrọ irinajo igbafẹ.
Koda, ‘NUBI -9JA’ eyi to ni orukọ Pelumi ninu ni nọmba ọkọ ti Sanwo-Olu fun un.
Ẹwẹ, Pelumi ti sọ pe oun yoo fi ọkọ oun, Lumi, ta ajọ ipinlẹ Eko to n ri si ọrọ aṣa ati ilẹ Yoruba lọrẹ gẹgẹ ẹbun.
Ninu ọrọ rẹ, Pelumi, ẹni ọdun mejidinlọgbọn lu ijọba ipinlẹ Eko lọgọ ẹnu lori bi wọn ṣe mọ riri rẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Pelumi Nubi tó wa ọkọ̀ láti ìlú London sí Nàìjíríà ti dé sí ìlú Eko

Ko si ohun ti o ni ibẹrẹ ti ko ni opin, alẹnulọrọ ori ayelujara, Pelu Nubi to n wa ọkọ lati ilu London si orilẹede Naijiria ti de si ilu Eko lonii ọjọ Aiku, ọjọ keje oṣu Kẹrin ọdun 2024 yii.
Ọgọọrọ eeyan lo lọ pade Pelumi lọgba ile ẹkọ giga fasiti UNILAG to wa niluu Eko lati ki i kaabọ lẹyin ti to wa ọkọ loju popo fun ẹgbẹrun mẹwaa kilomita lati orilẹede UK si Naijiria.
Ninu oṣu Kinni ọdun 2024 ni Pelumi gunle irinajo yii ninu eyi ti o ti gba orilẹede mẹtadinlogun kọja ki o to de Naijiria.
Pelumi ti sọ ṣaaju tẹlẹ pe oun gunle irinajo ọkọ wiwa lati ilu London si Naijiria lati fihan pe oun le ṣe nnkan nla gẹgẹ bi obinrin.
Ni ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹta ọdun yii ni Pelumi fi sori oju opo ayelujara rẹ wi pe oun ni ijamba ọkọ nigba to de orilẹede Liberia.
Aworan ọkọ rẹ fihan pe ọkọ naa maa nilo atunṣe ti yoo gba akoko ki o to le ri i lo pada.
Fidio ti o fi lede lori oju opo Instagram rẹ fihan bi wọn ṣe n gbe e lọ si ile iwosan fun itọju pẹlu ọkọ ambulansi.
Ijamba ọkọ yii ni ko jẹ ki Pelumi le pari irinajo rẹ lati London si Naijiria ninu oṣu Kẹta mọ, lẹyin ti gilaasi iwaju ati bọmba ọkọ naa bajẹ.
Ọpọ eeyan lo ro pe irinajo Pelumi ti tan lẹyin to ni ijamba ọkọ ni Liberia, amọ, o pinu lati tẹsiwaju irinajo naa si Naijiria.
Pelumi sọ ninu ifọrọwerọ kan pe oun gunle irinajo naa lati fun ọpọ eeyan ni igboya wi pe o ṣeeṣe ki eeyan wa ọkọ lati ilu London si Naijiria.
Pelumi ti o lanfani lati rinrin ajo lọ si orilẹede bi ọgọrin ṣalaye pe oun ṣe igbaradi fun irinajo naa lori ọna ti oun le gba ti ko ni mu ewu dani ati iye owo ti irinajo naa yoo na oun.
Wo aworan bi awọn ololufẹ Pelumi ṣe ki i kaabọ si Naijiria ni ọgba ile ẹkọ giga fasiti UNILAG ni ilu Eko lọjọ Aiku.



















