Ilé ẹjọ́ fún Godwin Emefiele ní béèlì l’Eko pẹ̀lú N50m

Ile ẹjọ to n gbẹjọ gomina banki apapọ Naijiria, CBN, tẹlẹ ri, Godwin Emefiele ti fun un ni beeli lonii ọjọ kejila oṣu Kẹrin ọdun 2024.
Adajọ Rahman Oshodi fun Emefiele ni beeli pẹlu N50n ati oniduro meji pẹlu iye owo kan naa.
Ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe awọn oniduro naa gbọdọ ni iṣẹ gidi lọwọ, ati wi pe wọn gbọdọ ni ẹri to fihan pe wọn n san owo ori fun ipinlẹ Eko fun ọdun mẹta.
Adajọ Oshodi sọ pe awọn oniduro naa gbọdọ ni nnkan idanimọ to muna doko.
Bakan naa ni adajọ sọ pe fifun Ọgbẹni Henry Isioma-Omoil to n jẹjọ pẹlu Emefiele ni beeli pẹlu N1m tẹ oun lọrun.
Isioma-Omoil tun n jẹjọ miran niwaju Adajọ Olufenke Sule-Hamzat ti ile ẹjọ giga to wa lagbegbe Yaba niluu Eko.
Ni ọjọ Aje ọsẹ yii ni ajọ EFCC to n gbogun ti iwa ibajẹ gbe Emefiele lọ ile ẹjọ l’Eko lori ẹsun iwa ibajẹ onikoko mẹrindinlọgbọn ati sisan $4.5bn ati N2.8bn jade lọna aitọ.
Ilé-ẹjọ́ gíga nílùú Eko pàṣẹ pé kí wọ́n fi Emefiele sí àhámọ́ EFCC lórí ẹ̀sùn jìbìtì $4.5bn

Oríṣun àwòrán, EFCC/Facebook
Ile ẹjọ to wa niluu Eko ti paṣẹ wi pe ki wọn fi Godwin Emefiele, gomina tẹlẹ ile ifowopamọ apapọ Naijiria, (CBN) si ahamọ ajọ EFCC.
Ileẹjọ paṣẹ pe ki Emefiele wa ni ahamọ naa titi di Ọjọbọ ọjọ kọkanla ti igbẹjọ lori ati gba beeli rẹ yoo waye nile ẹjọ.
Adajọ Rahman Oshodi tun paṣẹ pe ki Ọgbẹni Henry Omoile to n jẹjọ pẹlu Emefiele wa ni ọgba ẹwọn Ikoyi titi di Ọjọbọ ti igbẹjọ igbẹjọ mii yoo waye bakan naa.
Adajọ Oshodi paṣẹ yii lẹyin ti o gbọ awijare agbẹjọro awọn mejeeji, AbdulHakeem Labi-Lawal, lori ati gba beeli wọn tan.
Agbẹjọro Labi-Lawal rọ adajọ wi pe ko fi oju aanu wo Emefiele ati Omoile ki o si fun wọn ni beeli, amọ, ọrọ ko ri bẹẹ.
Ọgbẹni Rotimi Oyedepo to jẹ agbẹjọro ajọ EFCC ko tako ẹbẹ agbẹjọro awọn mejeeji, amọ, o rọ ile ẹjọ wi pe ki o ṣe ohun to ba ofin mu lori ẹbẹ naa.
Ẹsun iwa ibajẹ nigba to jẹ gomina CBN ni ajọ EFCC fi kan Emefiele, nigba ti ajọ naa fi ẹsun iwa ibajẹ onikoko mẹrindinlọgbọn kan Ọgbẹni Omoile .
This article contains content provided by Facebook. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Facebook cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Facebook post
Emefiele yóò tún fojú balé-ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn tuntun mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n lónìí
Yatọ si awọn ẹsun to ti n jẹjọ rẹ bọ, Godwin Emefiele, gomina tẹlẹ nileefowopamọ apapọ ilẹ wa, (CBN) yoo tun foju ba kootu lonii, ọjọ Aje, ọjọ kẹjọ oṣu kẹrin 2024, lori ẹsun mẹrindinlọgbọn tuntun.
Ile-ẹjọ giga to wa n’Ikẹja, l’Ekoo ni Emefiele yoo ti maa tẹsiwaju lori awọn ẹsun tuntun yii.
Diẹ lara awọn ẹsun naa bi EFCC ṣe fi kan an ni: gbigba owo abẹtẹlẹ, gbigba ẹbun lọwọ awọn eeyan, lilọwọ si iwa ajẹbanu, fifi èrú gba dukia ati fifun awọn ọmọ ẹyin rẹ lohun ti ko tọ si wọn.
Ọjọ Ẹti to kọja yii ni ajọ EFCC tun fi awọn ẹsun tuntun yii kan Emefiele, lẹyin to ti n jẹjọ iwa ajẹbanu ni kootu kan l’Abuja.
Emefiele yoo maa tẹsiwaju lori ẹsun kiko ọpọlọpọ biliọnu owo dọla sapo, ati aṣilo agbara.
Kí ló ti ṣẹlẹ̀ ṣíwájú?
Ọjọ Kẹsan-an oṣu kẹfa ọdun 2023 ni Aarẹ Bọla Tinubu da Godwin Emefiele duro gẹgẹ bi alaṣẹ CBN, ọjọ keji rẹ ni wọn si fi panpẹ ofin mu un.
Awọn ẹsun to foju han ju si araalu lori iwa Emefiele ni ti airowo naira na to ṣẹlẹ nibẹrẹ ọdun 2023.
Latari atunṣe 200, 500 ati 1,000 ti Emefiele ati Buhari, aarẹ igba naa gunle si ni eyi.
Ṣugbọn lẹyin ti ajọ EFCC bẹrẹ si i fi awọn ẹsun ọlọkan-o-jọkan kan an ni awọn eeyan ṣẹṣe n mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an.
BBC Yoruba yoo mu abajade kootu Emefiele wa loni lẹyin ijokoo kootu.














