Wọ́n dájọ́ ikú fún obìnrin tó lu bánkì ní jìbìtì $44bn

Aworan Truong My Lan

Oríṣun àwòrán, EPA

Obinrin kan ni orilẹede Vietnam, Truong My Lan, ni ile ẹjọ orilẹede Vietnam ti da ẹjọ iku fun bayii lori ẹsun pe o lu ile ifowopamọ kan ni jibiti $44bn.

Ile ẹjọ fidi rẹ mulẹ pe Lan lu ọkan lara banki to tobi julọ ni orilẹede naa ni jibiti owo ọhun laarin ọdun mọkanla.

Lan jẹ ọkan lara awọn obinrin ti o ti gba idajọ iku bayii lorilẹede Vietnam lori ẹsun iwa ibajẹ ni ọfiisi.

Arabinrin Lan jẹbi ẹsun pe o gba $44bn jade ni banki Saigon Commercial Bank gẹgẹ bi ẹyawo.

Ile ẹjọ dajọ wi pe ki o da $27bn pada ninu owo ọhun.

Ọpọ eeyan lo gbagbọ wi pe idajọ iku ti wọn fun un jẹ ọna kan gboogi ti ile ẹjọ fi n sọ fun un wi pe ki o da diẹ pada ninu owo naa.

Iroyin sọ pe eeyan to din diẹ ni ẹgbẹrun mẹta lo jẹri nile ẹjọ, nigba ti igba agbẹjọro kopa ninu igbẹjọ naa.

Igbẹjọ yii n ṣafihan ipinu akọwe agba ẹgbẹ oṣelu Communist Party, Nguyen Phu Trong lati gbogun ti iwa ajẹbanu ni Vietnam.

Eto igbogun ti iwa ibajẹ Communist Party naa ti jẹ ki aarẹ meji ati igbakeji olootu ijọba meji kọwe fipo silẹ.

Bakan naa ni ọpọlọpọ oṣiṣẹ ijọba ti dero ẹwọn.

Ni bayii, ọkan lara awọn to lowo julọ ni Vietnam tun ti gba idajọ iku.

Arabinrin Lan bẹrẹ owo ṣise nigba to bẹrẹ si ni ta ipara pẹlu mama rẹ, ṣugbọn o bẹrẹ si ni ra ilẹ ati dukia lọdun 1986.

Lan ti ni oriṣiiriṣii dukia bii ile itura ati ile ounjẹ igbalode nigba ti o di ọdun 1990.

Lootọọ ni ọpọ eeyan mọ Vietnam gẹgẹ bi orilẹede ti ọrọ-aje rẹ n dagba bi ti China, amọ, ọpọ awọn olowo orilẹede naa lowo nibi ṣiṣe owo kara kata ilẹ ati dukia.

Ijọba lo ni gbogbo ilẹ ni Vietnam, tori naa, awọn to ba mọ awọn to wa ni ijọba lo maa lanfani lati ra ilẹ.