Sodomy: Mo gbádùn ìbálọ̀pọ̀ pẹ̀lú ìbejì mí, mi ò lè gbà kí ó fẹ́ ẹlòmíràn''

Ibalopo

Oríṣun àwòrán, Others

Arakunrin Amos Kunde ni kani o ṣeeṣe lati yi ọwọ aago pada, oun yoo ṣe bẹẹ nitori iṣe ti oun ba ibeji oun ṣe buru jai kọja boṣe yẹ.

Kunde to sọ iriri bi oun ṣe bẹrẹ si ni ibalopọ pẹlu ibeji rẹ, ni o wu ohun ti oun gbagbe iṣẹlẹ naa.

Ibalọpọ laarin awọn mejeeji yii to waye ni agbegbe ijọba ibilẹ Guma, ni ipinlẹ Nasarawa ti jẹ ki wọn bi ọmọ meji fun ara wọn.

Kunbi ni idojuti gba a ni iṣẹlẹ naa jẹ fun oun, ti oun si pin nu lati gba awọn ọmọ meji oun, ki iyawo tuntun naa ma a tọju wọn.

Amọ ibeji oun, Juliana kọ jalẹ wi pe oun ko ni ni ọkọ miran, ekeji oun ti oun ti bi ọm meji fun un ni oun yoo fi ṣe ade ori.

Bi iriri wọ̀n ṣe lọ ni yii;

Arakunrin Patrick Kunde ati iyawo rẹ Torkwase lo parapọ n gbe ni agbegbe Awe ni ipinlẹ Nazarawa gẹgẹ bi agbẹ ko to di pe awọn Fulani darandaran ṣekọlu si wọn, ti wọn si pa awọn obi wọn ni ọdun 2013.

Awọn ibeji yii nikan ni wọn ye ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si sakuro ni agbegbe naa lọ si agbegbe tuntun.

Gẹgẹ bi ọmọ orukan,awọn ibeji naa Amos ati Juliana ti ko lọ si ileewe bẹrẹ iṣẹ ọgbin ni agbegbe Doku, to sun mọ ibode ipinlẹ Benue.

Iṣẹ agbẹ naa dara ni ọwọ wọn, ti wọn si ni ere oko to dara , eleyii to jẹ ki wọn duro ni agbegbe naa.

Laipẹ si igba naa ni wọn bẹrẹ ibalọpọ laarin awọn mejeeji, titi Juliana fi loyun ni ọdun 2015.

Ibeji

Oríṣun àwòrán, Others

Mo gbádùn ìbálọ̀pọ̀ pẹ̀lú ìbejì mí, mi ò lè gbà kí ó fẹ́ ẹlòmíràn''- Juliana

Wahala bẹ silẹ laarin awọn mejeeji lẹyin ti ibeji rẹ ọkunrin sọ fun un pe oun fẹ fẹ iyawo nitori ikeji oun lo jẹ.

Juliana ni oun yari nitori pe ki ni yoo jẹ ere oun ati awọn ọmọ meji ti oun bi fun ibeji oun.

Bakan naa ni oun ko le gba ki ẹlọmiran gbadun ibalopọ pẹlu ibeji oun, nitori o mọ ere se daradara lori ibusun.

Àkọlé fídíò, Se lootọ?: Wo irú sítàílì tó yẹ láti fi bẹ̀rẹ̀ ìbàlópọ̀ lẹ́yìn ìbímọ- Tola Ajayi

Juliana to sọ iriri rẹ lori bi wọn ṣe bẹrẹ ibalopọ naa ni inu oko ni awọn wa nigba ti sokoto ti ekeji rẹ wọ ja ni abẹ lasiko to fẹ jẹun, to si bẹrẹ si ni fi ṣe yẹyẹ pe nkan ọmọkunrin rẹ tobi ju bo ṣe lọ, ti ekeji rẹ naa si rẹrin.

''Lalẹ ni Amos wa si ibi ti mo wa to si bere ''blade'' ni ọwọ mi amọ nko bo ara mi daadaa, ti a si bẹrẹ si ni ṣere ifẹ

''Ọdun 2015 ni mo kọkọ ni oyun, ti mo si tiraka lati yọ amọ o jasi pabo.''

''Lẹyin naa ni wọn kuro ni agbegbe naa, nitori naa ni ko si ẹni to mọ nitori mo sọ fun wọn pe ẹni to fun mi ni oyun ti salọ.''

''Amọ lẹyin ọmọ keji ni Amos ni oun fẹ fẹ iyawo to wu ohun ki oun wa ọkọ tirẹ naa si iwaju.''

''Mi o le gba lailai nitori mo ti de waasimi , mi o si le e jẹ ki obinrin miran gba iṣe mi ṣe tabi ni ibalopo pẹlu ibeji mi''

Ninu hila-hilo yii ni awọn mejeeji wa ti Juliana fi tu asiri ohun ti wọn ṣe ti ile fi jona sita.

Àkọlé fídíò, TolaSex style and danger in pregnancy: Irú sítàílì ìbálòpọ̀ wo ló n jẹ́ kí oyún tètè dúró?

Irọ ni, ibeji mi lo kọkọ gbe ibalopọ sun mọ mi, ti esu si ranmilọwọ - Amos

Lasiko ti Amos n sọ iriri tirẹ ni oun ibanujẹ ni iṣẹlẹ naa jẹ fun oun, ti oun ko si mọ ohun ti ohun le ṣe si.

Amos ni ibeji oun lo gbe ibalopọ sun mọ oun nitori ko ki n wọ aṣọ ninu ile, ti yoo si ṣi abẹ rẹ silẹ nibi ti oun ti lọ ma n fun awọn adiyẹ oun ni ounjẹ.

O ni ni alẹ ọjọ ti awọn bẹrẹ ni Juliana ṣi idi silẹ, ti oun si ri nkan ọmọbinrin rẹ pe o tobi, ti awọn si fi ṣere ko to di wi pe ọrọ yiwọ, ti awọn si bẹrẹ si ni ba ara awọn sun.

Àkọlé fídíò, Pneumonia: Dókítà ní kòkòrò àìfojúrí ló ń fàá

Awọn mejeeji ni wọn sọ wi pe awọn gbadun rẹ, amọ Amos n bẹru pe awọn ọmọ naa le ku nitori eewọ ni ohun ti awọn mejeeji ṣe.

Adari agbegbe naa to ni pe awọn yoo wa ọna abayọ si i iṣẹlẹ naa ni awọn ko le e fi to ẹṣọ alaabo leti nitori ọrọ naa ti kọja iru rẹ.