2021 Twin Festival: Aráàlú ní Ifá ló sọ pé ìbejì yóò pọ̀ ní Igboora, kìí ṣe jíjẹ Ìlasa

Àkọlé fídíò, 2021 Twin Festival: Aráàlú ní Ifá ló sọ pé ìbejì yóò pọ̀ ní Igboora, kìí ṣe jíjẹ Ìlasa

Ajọdun ọdun ibeji to waye ni ọdun 2021 dun, to si larinrin pupọ nitori awọn eeyan jankan-jankan to peju sibẹ, to fi mọ Alaafin tilu Oyo, Oba Lamidi Olayiwola Adeyemi Kẹta.

Ninu ifọrọwerọ ti BBC Yoruba se fawọn ibeji ati araalu ni wọn ti salaye idi ti awọn ibeji se pọ silu Igboora ati ohun to fa sise ajọdun naa lọdọọdun.

Lara awọn ibeji to ba BBC Yoruba sọrọ lo koro oju si bi awọn obi kan se maa n gbe awọn ibeji jo kiri lati se agbe jẹun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn ibeji naa ni eyi ko dara to rara nitori awọn ibeji kii se olosi tabi alagbe ọmọ, ti wọn si n ke si ijọba lati se ofin ti yoo pa asa naa rẹ.

Bakan naa ni awọn araalu sọ pe ero awọn eeyan kan to ni bi wọn se maa n jẹ ọbẹ Ilasa to wọpọ julọ nilu Igboora, lo mu ki wọn maa bi Ibeji ko tọna rara.

Awọn kan ni Ifa lo ti kọkọ kede saaju pe ilu naa yoo gbajumọ fun bibi Ibeji lorilẹ aye, eyi to n wa si imusẹ bayii.

Awọn miran ni eeyan le jẹ ọbẹ Ilasa lai ma bi ibeji amọ ti eeyan ba mu omi ilu Igboora sori ounjẹ naa, eroja mejeeji yii ni yoo parapọ lati mu ibeji wa.

Ẹkunrẹrẹ fidio bi ọdun ibeji se lọ nilu Igboora lọdun 20121 ree, ẹ wo o.