University of Ibadan new VC: Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyebode Adebowale, gíwá tuntun ní fásitì Ibadan

Oríṣun àwòrán, other
Igbimọ iṣakoso fasiti ilu Ibadan ti yan Ọjọgbọn Kayọde Oyebọde Adebọwale gẹgẹ bi Giwa tuntun fun ile ẹkọ giga naa.
Igbimọ naa labẹ idari Oloye John Odigie-Oyegun buwọlu orukọ Ọjọgbọn Adẹbọwale gẹgẹ bi giwa kejila fun fasiti naa to ti pe aadọrin ọdun lẹyin ti ipo naa ṣofo ni ọjọ kini oṣu kejila ọdun 2020.
Oloye Odigie-Oyegun ṣalaye ninu atẹjade kan to fọwọsi pe eeyan mẹrindinlogun lo dide fun ipo naa ki wọn to yan Ọjọgbọn Adẹbọwale.
Ta ni Ọjọgbọn Kayọde Oyebọde Adebọwale?
- Ni ọjọ kọkanla oṣu kini ọdun 1962 ni wọn bi ọjọgbọn Adebọwale. O kẹgbọ gboye imọ ijinlẹ akọkọ, ekeji ati oye ọmọwe, (BSc, MSc ati PhD) ni fasiti ilu Ibadan.
- Lọdun 2006 lo di Ọjọgbọn ninu imọ Industrial Chemistry. Bakan naa lo tun gba imọ kun imọ nileewe fasiti Ebehards Karls University, Tuebingen lorilẹede Germany, pẹlu Abdus Salam International Centre for Theoretical Physics ni Italy.
- Oniruuru amiẹyẹ lo ti gba ninu eyi ti Fellow, Nigeria Academy of Science, Polymer nstitute of Nigeria, Chemical Society of Nigeria and Science Association of Nigeria. Fellow Royal Society of Chemistry, Alexander von Humboldt Stiftung ati, African Academy of Science to gba laipẹ yii wa.
- Oniruuru aṣeyọri iwadii ims ijinlẹ lo si ti gunle, ti ọpọlọpọ awọn akẹkọọ lẹka imọ fasiti gbogbo si ti bu mu ninu omi ọgbọn rẹ pẹlu.
- Oun ni igbakeji Giwa fasiti naa to n mojuto eto akoso, (Deputy VC Admin) ṣaaju ipo tuntun ti wọn yan an fun yii.








