Facebook: A óò gbégilé ojú òpó ẹnikẹ́ni tó bá dẹ́yẹ sí ẹlòmíràn nítorí ẹ̀yà ara ìbálòpọ̀ lójú òpó wa

Oríṣun àwòrán, Mark Zuckerberg
Oju opo ikansiraẹni Facebook ti ni awọn yoo bẹrẹ si ni gbegile oju opo to ba dẹyẹ si awọn eniyan nipa ẹya ara ibalopọ ti wọn ni, paapaa awọn gbajumọ lawujọ.
Olori ẹka to n risi ọrọ aabo lori ikansiraẹni Facebook, Antigone Davis lo fi lede bẹẹ ni oju opo naa.
Davis ni igbesẹ yii jẹ ọna tuntun lati koju oniruuru ipenija idẹyẹsini to n waye ni oju opo ikansiraẹni Facebook.
- Ẹ wo bí arákùnrin kan ṣe fi ọrún àti ọfà pa èèyàn márún ún
- "Akitiyan wa ti ń so èso rere, àdínkù ti ń bá bí àwọn agbésùmọ̀mí ṣe ń kọlu àwọn ọmọ Naijiria"
- "Á fimú Odunlade Adekola dánrin tó bá kọ̀ láti ṣe àtúnṣe lórí títàbùkù ẹ̀sìn Islam nínú fíìmù rẹ̀"
- Ọ̀lọ́pàá 34,587 níjọba àpapọ̀ ń rán lọ Anambra láti kojú agbébọn tó bá gbémú
- Wo aṣòfin àpapọ̀ tó fẹ́ káwọn káfíńtà àti dẹ́rẹ́ba ọlọ́kọ̀ èrò má san owó orí, Ó ní owó kékéré kó ni wọ́n rí
- Buhari, wá nǹkan ṣe sí àwọn agbésùmọ̀mí àti agbébọn tó ń pẹ̀ka bí ìrókò-Afenifere
- Iyorchia Ayu di alága tuntun fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP
- A pinu láti sinmi díẹ̀ lẹ́yìn ìgbeyàwó ká tó bímọ àmọ́ ó yíwọ́ - Wumi Toriola
- Wo bí àṣà ìbálé lálẹ́ ìgbeyàwó ṣe ń dọdẹ àwọn obìnrin òde òní kiri
O ni igbesẹ tuntun naa yoo koju ipenija idẹyẹsi si ni ati sisọ ọrọ kubakugbe lori ẹrọ ayelujara.
'' Igbesẹ tuntun naa yoo yọ ẹnikẹni ati oju opo awọn awujọ ati ẹgbẹ to ba tapa si ofin nipa didẹyẹ si ni nitori ibalọpọ lọna ati tabuku awọn eekan lawujọ, oloṣelu, gbajumọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.''
''Ofin tuntun naa fofin de yiya aworan ibalopọ ati ati ṣise apejuwe lọna ati dẹyẹsi ẹya ara ibalopọ.''
''Bakan naa ni oju opo Facebook yoo yọ ẹnikẹni to ba sọrọ kugbakugbe nipa ibalopọ ẹnikẹni, ti o si n dunkoko mọ ẹni naa nitori ẹya ara ibalopọ rẹ.''
''A mọ wi pe ọpọlọpọ eniyan lo n lo oju opo ikansiraẹni yii to fi mọ awọn oloṣelu, akọroyin, gbajumọ, ilumọọka ati awọn to n ṣiṣẹ lori ẹrọ ayelujara ni wọn n lo lati fi ba awọn eniyan wọn ati alatilẹyin wọn sọrọ.''
Facebook fikun pe nitori naa ni awọn ṣe gbe igbesẹ yii nitori awọn eniyan n lo idẹyẹsini nipa ẹya ara ibalopọ lati fi ba orukọ ẹlomiran jẹ.
Ileeṣẹ Facebook ni lọpọ igba ni awọn to n dẹyẹsi ẹnikeji wọn kuna lati fi oju ara wọn lede, ti wọn si n ba iṣẹ ẹlomiran jẹ.














