Odunlade Adekola: THURIST ní tó bá jẹ́ apá òkè ọya ni wọ́n ti tàbùkù Islam, wàhàlà yóò ti bẹ́ sílẹ̀

ODUNLADE ADEKOLA

Oríṣun àwòrán, odunladeadekola

Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ mùsùlùmí kan tó ń jẹ́ Ta'awunu Human Right of Nigeria, THURIST, ti sọ pe awọn yoo fi imu oṣere tiata Yoruba, Odunlade Adekola danrin, to ba kọ lati ṣe atunṣe lẹyin to tabuku ẹsin Musulumi ninu fiimu rẹ kan.

Agbẹjọro ẹgbẹ naa, Sulayman A. Tadese lo sọ ọrọ naa lasiko ifọrọwerọ kan pẹlu BBC Yoruba.

Bẹẹ ba gbagbe, a mu iroyin kan wa fun lọjọru nibi ti ẹgbẹ Musulumi Thurist ti fọnmu pe Odunlade Adekola tabuku awọn obinrin musulumi to n da asọ boju ninu sinima kan to gbe jade, eyi to pe akọle rẹ ni Iku Ni.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ẹsin Musulumi lo ni aṣa ki obinrin maa da aṣo bori, ṣugbọn ko tọ ki awọn oṣere maa tabuku ẹsin awọn Musulumi ninu ere tiata.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni "A kọ iwe si Odunlade, TAMPAN atawọn mii ti ọrọ naa kan lori bi Odunlade ṣe tabuku ẹlẹha kan ninu fiimu rẹ."

Ni ti pe ere lasan ni ọrọ naa ati pe ko yẹ ko di wahala, Tadese ni ko si ọrọ awada ninu ẹsin Musulumi.

Àkọlé fídíò, Adejoke Ewaede: Ìfẹ́ àṣà Yorùbá ló mú kí ń pinnu láti máa wọ aṣọ àdìrẹ̀ nìkan

Agbẹjọro naa ṣalaye pe "Ere wa lara awọn nnkan to le di ogun, ati pe ohun to ba ti jọ mọ ọrọ ẹsin ko ni ere ninu."

"To ba jẹ pe apa oke ọya ni wọn ti ṣe irufẹ nnkan bayii ni, wahala yoo ti ṣẹlẹ, ṣugbọn ọrọ naa ko tii di wahala nitori pe ilẹ Yoruba ni a wa."

Tadese sọ siwaju si pe awọn Musulumi kan lo wa fi ọrọ naa to awọn leti ki awọn to gbe igbesẹ lori rẹ.

Bí Odunlade ati TAMPAN ko ba se ohun ta fẹ, ohun ta se fun wọn wa ninu wa:

Ni ti ohun ti wọn fẹ ki Odunlade ṣe lori sinima naa bayii, agbẹjọro THURIST sọ pe awọn n fẹ ki wọn dẹkun gbigbe fiimu naa jade.

O ni "Lakọkọ na, ohun ti a fẹ ni ki wọn má gbe fiimu naa jade mọ, ẹlẹẹkeji ni pe a fẹ ki wọn tọrọ aforiji lọwọ gbogbo Musulumi Naijiria."

"Ohun ti a maa ṣe lẹyin ọjọ meje wa ninu wa, to ba kọ lati ṣe ohun ti a n beere fun, o le ma jẹ ile ẹjọ ni a maa gbe lọ ṣugbọn a maa gbe igbesẹ pataki lori rẹ."

Bo tilẹ jẹ pe o ni awọn ko gbogun ti Odunlade Adekola nitori kii ṣe ẹlẹsin Musulumi, o ni to ba jẹ pe Musulumi lo dan iru rẹ laṣa, yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

Ẹwẹ, BBC Yoruba kan si Aarẹ ẹgbẹ awọn oṣere tiata, TAMPAN, Bolaji Amusan ti ọpọ eeyan mọ si Mr Latin lati mọ ero rẹ lori isẹlẹ yii, o ni oun yoo sọrọ lori ẹsun naa ati igbesẹ ti awọn yoo gbe lori rẹ laipẹ.

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́