Adejoke Ewaede: Ìfẹ́ àṣà Yorùbá ló mú kí ń pinnu láti máa wọ aṣọ àdìrẹ̀ nìkan

Àkọlé fídíò, Adejoke Ewaede: Ìfẹ́ àṣà Yorùbá ló mú kí ń pinnu láti máa wọ aṣọ àdìrẹ̀ nìkan

Yoruba ni ọmọ to sọ ile nu, o so apo iya kọ, bẹẹ si ni ẹnikan kii fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ.

Obinrin kan ree, Adejoke Somoye, ti ọpọ eeyan mọ si Adejoke Ewaede lori ayelujara to yan itọju ede ati asa laayo.

Adejoke tii se sọrọ-sọrọ lori redio ni ohun to n ba oun lọkan jẹ ni bi awọn ọdọ se n pa asa ati ede abinibi wa ti, ti wọn si n yan awọn asa ajeji laayo.

Ninu ifọ̀rọ̀werọ̀ rẹ́ pẹ́lu BBC Yoruba, o fikun pe ifẹ si asa ati ede ilẹ Yoruba lo mu ki oun pinnu lati mase fi asọ miran kan ọrun oun mọ yatọ si asọ ti wọn fi aro se ta n pe ni adirẹ.

Onimọ nipa asa Yoruba naa ni nnkan ti bajẹ jinna lori ede ati asa wa, to si n rọ awọn oriade nilẹ Yoruba lati dide daabo bo asa ati ede wa ko ma ba parun.

Adejoke ni o se ni laanu pe wọn kii sọ ede Yoruba ninu aafin, to si n gba awọn ọba alade nimọran lati pọn sisọ ede Yoruba ninu aafin ni dandan fun gbogbo eeyan.

Obinrin agbasaga naa wa da laba pe ki awọn eeyan maa tabuku ọmọ Yoruba ti ko ba le kọ tabi sọ ede rẹ daadaa nitori awọn naa maa n kan ẹni ti ko ba le sọ ede gẹẹsi daadaa labuku.