Romeo and Juliet padà di ìwé Akinola àti Arike ní èdè Yorùbá

Àkọlé fídíò, Romeo and Juliet padà di ìwé Akinola àti Arike ní èdè Yorùbá

Ko fẹ si akẹkọọ imọ nipa ẹkọ Litiresọ, ti ko ni ka iwe itan ololufẹ meji kan ti wọn pe ni Romeo and Juliet eyi ti akọni onkọwe nni, William Shakespeare kọ.

Amọ nitori awọn ogbontagi gẹẹsi atijọ to fi kọ iwe naa, o loju akẹkọọ tabi onkawe ti itan naa ye bo se yẹ amọ anfaani ọtun tun ti de lati gbadun itan ifẹ naa.

Idi ni pe iwe naa ti yipada di iwe ìtan ifẹ Akinola ati Arike ni ede abinibi tiwa, Yoruba.

Yatọ si eyi, ọpọ asa, ẹwa ede ati ise Yoruba tun ni wọn ti bọ iwe yii, ti yoo tubọ mu ko dun, ko si ni arinrin leti ẹni to ba ka a.

BBC Yoruba wa nibi ikojade itan ifẹ Akinola ati Arike yii, ti wọn se ni ere onise.

Bakan naa, a tun ba awọn eeyan to se agbatẹru iwe kika ati ere onise naa sọrọ lori ohun to pilẹ igbesẹ yii.

Fun igbadun isinmi opin ọsẹ yin, ẹ wa daraya pẹlu ere onise yii, Akinola ati Arike.