Seyi Makinde: Ọmọ ẹgbẹ́ PDP Oyo tó bá ń bínú, ẹ kó mo kó mo rò yín wá ká yanjú ẹ̀

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde
Laarin gbọnmi sii omi o to eyi to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party igun ti ipinlẹ Oyo, Gomina Seyi Makinde ti parọwa si gbogbo ọmọ ẹgbẹ fun ibagbepọ alafia.
Eyi waye gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu naa ṣe ṣe eto idibo wọọdu wọn to waye lọjọ Ẹti ni ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn.
Iroyin ni gbogbo idibo naa waye ni irọwọ ohun irọsẹ eyi ti Makinde si fi anfani naa fun'pe si awọn to ṣi n ni ikusinu sira ninu ẹgbẹ lati gba ifọrọjomitoro ọrọ ati ipẹtusaawọ laye.
"Fun awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Oyo, mo fẹ sọ fun wọn ki wọn wa ni isọkan tori ohun taa le ṣe pọ taa ba wa ni irẹpọ. Fun awọn to n ni ikunsinu tabi binu, ẹ jẹ ki wọn gbe mo ko - mo ro wọn wa siwaju wa, a o boju wo o".
Makinde ni agbe ma ja kan o si, ka ja ka pari rẹ ni ọrọ oṣelu. Nigba to boju wo bi ero ṣe tu jade kẹti kẹti fun idibo ọhun, o ni inu oun dun pe inu awọn ara Oyo dun si ẹgbẹ oṣelu to wa lori oye nipinlẹ naa.
- Àgùnbánirọ̀ Fidelia ti sọ irú ìdájọ́ tó ń fẹ́ fún sọ́jà tó da omi ìdọ̀tí lé e lórí
- Ó ṣeéṣe kí àwọn òkú lẹ́tọ́ láti dìbò lọ́dún 2023, ìdí rèé gẹ́gẹ́ bí àjọ INEC ṣe sọ
- Wo ewu tó wà nínú fífi ọ̀sẹ̀ fọ ojú ara fún ọkùnrin àti obìnrin
- Ọkùnrin kan tó jẹ gbèsè N4.6m ni wọ́n so mọ́lẹ̀ bíi ewúrẹ́
- Wo ìdí tí àwọn tọkọ-taya kan ṣe ń ṣe ìgbéyàwó nínú pósí
Nibayii, awọn adari ẹgbẹ oṣelu PDP ti yan igbakeji Gomina ipinlẹ Edo, Philip Shaibu gẹgẹ bi alaga igbimọ wọọdu ni Oyo.
Shaibu ni igbimọ naa ko tilẹ ri apẹẹrẹ ija tabi aawọ kankan tori eto idibo naa lọ ni irọwọ irọsẹ.
O fi aridaju han pe ẹgbẹ naa yoo yanju gbogbo ija abẹle to n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ni tubu n nubi.
Bi ẹ ko ba gbagbe, aawọ inu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party ni Oyo ti n fi sihin sọhun lati igba diẹ sẹyin to bẹẹ ti awn ọmọ ẹgbẹ kan kọwe titi d'oke ko tẹ awọn lọrun bi Gomina Seyi ṣe n tukọ ẹgbẹ naa.
Ko fibẹẹ wọpọ ki ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ dibo pe awọn ko nifẹ si ohun ti Gomina wọn n ṣe amọ eyi ṣẹlẹ ni Oyo.
Igun kan ninu ẹgbẹ naa ni Seyi Makinde ko faaye gba ẹtọ awọn ọmọ ẹgbẹ to n fori ṣe lọsan ati loru ati pe o n yẹyẹ wọn o tun n ko iyan wọn kere.
Ẹwẹ, gomina Seyi Makinde to ri bi awọn ẹgbẹ ṣe wa tu jade lọjọ Satide fun idibo naa, ọkan rẹ walẹ pẹsẹ to si bẹrẹ si ni pe fun ibaṣepọ laarin ọmọ ẹgbẹ.

















