Lagos Police: Ọwọ́ sìnkún ọlọ́pàá tẹ ọkùnrin tó so onígbèsè rẹ̀ mọ́lẹ̀ pẹ̀lú igi

Oríṣun àwòrán, Lagos State Police Command
Ọba Oke jọọ ma se jẹ ka sẹ ẹni ti ko ni gbọ ẹbẹ tabi tẹni ti ika.
Ileesẹ Ọlọpaa ipinlẹ Eko ti doola ẹmi ọkunrin kan, Reuben Alozie, to jẹ gbese miliọnu marun din ni irinwo naira (N4.6m) lọwọ ẹni to jẹ lowo, Oluchi Okoye.
Okoye, ti ọpọ eeyan tun mọ si PACA lo jẹ oludari ileesẹ kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- 'Eniola Badmus wọ pátá lọ sí ààfin Oba Elegushi, "ọ̀ín" kí ló burú níbẹ̀?'
- Ọmọ ẹgbẹ́ PDP Oyo tí inú bá ń bí, ẹ kó "mo kó - mo rò" yín wá ká yanjú ẹ̀ - Makinde
- Èèmọ̀ wọ̀lú! Àrá sań pa bàbá, ìyá àti ọmọ wọn méjì
- Àlàyé rèé lórí bí sọ́jà ṣe lu àgùnbánirọ̀ obìnrin, tó da omi ìdọ̀tí le lórí
- "Ìgbéyàwó wa pé ọdun mẹ́ẹ̀dógún, àmọ́ ìgbà mẹ́wàá péré la ní ìbálòpọ̀"
- Wo owó ilẹ Adúláwò mẹfà tó ń figagbága pèlú owó Dọlà America...
- Ajá gé ǹkan ọmọkùnrin akẹkọọ AAUA ní Akungba jẹ ní àwọn agbófinró bá mú ajá náà
- Ọ̀gá ọlọ́pàá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí wọ́n lọ fi ṣìkún òfin mú àwọn ọlọ́kadà nílùú Eko
- Wo ìdí tí àwọn tọkọ-taya kan ṣe ń ṣe ìgbéyàwó nínú pósí
Alozie to jẹ Okoye ni gbese ni wọn so mọlẹ bii ẹran amọ ti ori ko yọ nigba ti awọn ọlọpaa gba silẹ, ti wọn si mu Okoye, ẹni to jẹ ni gbese naa.
Gẹgẹ bi atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Adekunle Ajisebutu fisita, se ni Okoye so onigbese rẹ mọ igi kan bii ewurẹ.

Oríṣun àwòrán, Lagos State Police Command
Gẹgẹ bi atẹjade naa ti wi, ojule kọkandinlọgbọn, opopona Abeokuta ladugbo Ebute Metta nilu Eko, ni isẹlẹ naa ti waye.
Ileesẹ ọlọpaa fikun pe odidi ọjọ kan gbako ni Okoye fi so Alozie mọlẹ bii ẹran, laarin Ọjọru, ọjọ Kejilelogun si Ọjọbọ, ọjọ Kẹtalelogun osu Kẹsan ọdun 2021.
Iroyin naa ni ọpẹlọpẹ ileesẹ ọlọpaa to lọ sinu ile naa lati lọ doola ẹmi Alozie, bi bẹẹ kọ, ẹmi rẹ le bọ sinu isẹlẹ yii.
Nigba to n salaye ohun to ri lọbẹ, to fi waru sọwọ, afurasi naa, Oluchi Okoye ni oun se idajọ lọwọ ara oun nitori gbogbo iyanju oun lati gba owo ti Alozie jẹ oun lo kuna.
Ileesẹ ọlọpaa ni iyawo Alozie ti wọn so mọlẹ, Angela Reuben lo mu ẹsun wa agọ ọlọpaa pe Okoye ti mu ọkọ oun lẹru, ti ko si jẹ ko ni ominira kankan rara.
Kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu ti wa pasẹ pe ki wọn gbe afurasi naa lọ si ẹka iwadii ileesẹ ọlọpaa fun ẹkunrẹrẹ iwadii ati igbẹjọ.
Odumosu tun wa fi ewe ọmọ mọ awọn araalu leti lati maa tọ ipasẹ ofin dipo sise idajọ lọwọ ara wọn

















