Lightning kills family: Àrá sań pa èèyan mẹ́rin nínú ìdílé kan ṣoṣ

Lightning strike

Oríṣun àwòrán, jplenio

Ara ti san pa eeyan mẹrin lati inu idile kan naa lagbegbe Muleba, Lake Victoria lorilẹ-ede Tanzania.

Agbẹnusọ fun agbegbe Muleba ti iṣẹlẹ naa ti waye, Thoba Nguvilla sọ nibi ipade awọn akọroyin kan pe ara ọhun san pa awọn mọlẹbi naa lalaẹ Ọjọbọ.

O ni tọkọ-taya atawọn ọmọ wọn ni ara naa san pa.

Nguvilla sọ siwaju si pe iṣẹ agbẹ ati apẹja ni awọn mọlebi naa yan laayo, ki iṣẹlẹ ibi ọhun to waye.

Ẹwẹ, alaga abule ti wọn n gbe, Robert Musiibah ṣalaye pe ina sọ lara orule ile wọn, ti ile naa si jona lasiko iṣẹlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Romeo and Juliet padà di ìwé Akinola àti Arike ní èdè Yorùbá

Kii ṣe igba akọkọ ree ti ara yoo san pa awọn eeyan nilẹ Afrika.

Nilẹ Yoruba, igbagbọ ọpọ eeyan ni pe irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ kii ṣe oju lasan, paapaa ti wọn ba ti kọkọ fi ẹsun ole jija kan ikankan ninu awọn mọlẹbi naa.

Ṣugbọn awọn mii tun gbagbọ ohun gbogbo kọ lo lọwọ aye ninu nitori awọn nnkan miran maa n ṣadede waye.

Àkọlé fídíò, Awo Stage Play: Wo eré, ijó àti orin tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ayé Awolowo àti aya rẹ̀