Top six Africa's strongest currencies: Àwọn owó ilẹ Afrika tó ń bá owó dọlà figagbága lásìkò yìí

Money

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gbogbo ohun to ba eto ọrọ aje kaakiri agbaye kọja sisọ lasiko yii paapaa lẹyin isẹlẹ ajakalẹ arun Coronavirus.

Opọlọpọ orilẹ-ede ni nkan ko sẹnu rere fun eto ọrọ aje wọn mọ nilẹ Adulawọ.

Bi ko se si owo to lati na naa ni awọn eeyan n kun fun airisẹse.

Owo dọla ilẹ Amerika je eyi to se pataki lagbaye lati fi sodiwọn iye gbendeke owó Naijiria.

Diẹ lara awọn owo ilẹ Adulawọ to si n figagbaga pẹlu dọla ni agbaye ree:

1: Libya Dinar (1 USD = LD 1:41):

Owo ti wọn n na ni orilẹ-ede Lybia, Dinar si duro gidi laarin awon owo ilẹ Adulawọ lasiko yii.

Dola kan ni wọn fi n se Dinar Libya kan ati ogoji le kan.

2.Tunisia Dinar (1 USD = DT 2: 87):

Orilẹ-ede Tunisia wa ni ariwa Afrika bii ti Libya . Lọwọlọwọ bayii owo dola kan ni wọn fi n se owo Dinar Tunisia meji ati ogorin le meje

Àkọlé fídíò, Awo Stage Play: Wo eré, ijó àti orin tó ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ayé Awolowo àti aya rẹ̀

3.Ghana Cedi (1 USD = GH 5. 49):

Owo ile Ghana lo n lewaju ni apa Afrika ti a wa yii.

Owo dola kan ni wọn fi n sẹ Cedi marun un ati mokandinlaadota.

Eyi ni owo Iwọ Oorun Ile Afrika to lagbara julo ninu awon orile ede Iwo Oorun ile Afrika.

4.Morocco Dirham (1 USD = MAD 9:20:

Eyi ni owo dola America kan to je Dirham Morocco mesan an ati ogun.

Money

Oríṣun àwòrán, naijanews

5 . South Africa Rand (1USD= R14:87):

Owo ile South Africa, Rand naa tun gbe soke.

Orilẹ-ede yii lo n pese goolu julo ni Afrika, Oun naa lo tun n lewaju pelu owo dola kan si Randi meedogun din die.

6: Egypt Poun (1USD = E£ 15.86):

Orile-ede Egypt ti diju gbe awọn igbese akọni kan lati jẹ ki owo ilẹ wọn le gbe pẹẹli sii.

Eyi si ti jẹ ki owo pasipaaro wọn si dọla jẹ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: