Husband Searcher: Obìnrin náà ní òun yóò san owó orí ọkọ òun, ti òrùka ìgbeyàwó

Obinrin to n wa ọkọ pẹlu akọle lọwọ

Oríṣun àwòrán, Screen Shot

Ara meeriri kan ree o, a ri ori ologbo lori atẹ, Yoruba sa ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bi eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.

Bo se ri ree pẹlu obinrin wundia kan to wọ asọ igbeyawo maa kiri oju popo pe oun n wa ọkọ ti yoo fẹ oun sile, eyi to fun ọpọ eeyan niran wo.

Isẹlẹ yii si lo waye lagbegbe Buza nilu Dares Salam lorilẹede Tanzania, nigba ti obinrin naa gbe akọle kan lọwọ lati salaye pe oun n wa ọkọ ti yoo fẹ oun nitori ọjọ ti n lọ lori oun.

Fidio kan to gba awọn oju opo ayelujara kan lo se afihan obinrin naa pẹlu akọle to n salaye iru ọkọ to fẹ fẹ.

Gẹgẹ bi akọle naa ti wi, obinrin naa ni oun n wa ọkọ ti ọjọ ori rẹ wa laarin ogun ọdun si aadọrin ọdun, ti oun si setan lati san owo ori iru ọkunrin naa.

Àkọlé fídíò, Hospital Wedding: Oṣù kan péré ni Tash fi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Simon kó tó kú

Bakan naa lo fi kun pe oun ti ra oruka igbeyawo pamọ eyi ti oun ati ọkunrin to ba gba lati fẹ oun yoo lo lati se igbeyawo.

Obinrin naa to wọ asọ igbeyawo tun sisọ loju rẹ pe ẹgbẹrun lọna mejilelogoje sile owo ilẹ Tanzania.

O fikun pe ẹlẹsin Kristiẹni ni oun amọ oun setan lati di ẹlẹsin musulumi to ba jẹ ọkunrin to fẹ fẹ oun jẹ ẹlẹsin Islam.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni irufẹ ọkunrin naa gbọdọ ni ibẹru Ọlọrun lọkan, ko si tun ni itẹriba pẹlu, to si tun gbọdọ ni ifẹ oun pupọ.

Obinrin ọhun wa fi ọwọ gbaya pe owo ko ni jẹ isoro awọn nitori Ọba Oke fi owo da oun lọla pupọ.

Yatọ si eyi, obinrin naa ni oun yoo maa lọ kaakiri awọn agbegbe to wa lorilẹede naa, lati kede pe oun n wa ade ori.

Àkọlé fídíò, Toríi "Coro", ẹ wo bí ètò ìsìn ìgbéyàwó orí ayélujára Zoom ṣe lọ