Divorce in Ibadan: Iléẹjọ́ tú ìgbéyàwó ọdún méjé ká nítorí àìnáání ara ẹni

Oríṣun àwòrán, Nigerian Observer
Ilẹejọ Mapo Customary Court ni ilu Ibadan ti tu igbeyawo ọdun meje ka laarin Abiola Giwa ati ọkọ rẹ lori ẹsun pe ko naani iyawo rẹ.
Ninu ọrọ rẹ, Giwa to jẹ iya ọmọ kan ke si ileẹjọ lati tu igbeyawọ oun ka nitori ọdun mẹrin ni ọkọ oun fi fi oun silẹ lai wẹyin wo.
Oloye Ademola Odunade lasiko to n sọ idajọ rẹ ni oun tu igbeyawo naa ka ki alaafia le jọba.
- AbdulQudus Bello ṣàlàyé bí òun ṣe dí aláàbọ̀ ara nítorí pọpọ́ọ̀fù àti ìbínú jàǹdùkù àdúgbò
- Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó wáyé nínú oṣù Kẹ́wàá ọdún 2020
- Wo ìgbà márùn ún tí Buhari ti rìnrin àjò lọ sókè òkun fún ìtọ́jú ara rẹ̀
- Buhari, dẹ́kun à ti máa lọ sókè òkun fún ìtọ́jú, tún ilé ìwòsàn Aso Rock ṣe- Sẹ́nátọ̀
Odunade ni iwadii fihan wi pe ko si ohun ti ileẹjọ le ṣe mọ, afi ki wọn tu igbeyawo naa ka nitori arabinrin Adebimpe naa buwọlu igbesẹ naa.
Giwa ni '' ni ọdun meje sẹyin ti a ṣe igbeyawo tan, ni Adebimpe mu mi lọ si ile ahoro kan, to si fimisilẹ nibẹ.''
''O fi ọrọ ranṣẹ si mi pe ki n ko jade kuro nibẹ lọ si ile awọn obi oun nitori oun ti loyun''
''Fun ọdun mẹrin, mi o gbọ nkankan lati ọdọ rẹ, mo tọju ọmọ mi lai ri iranwọ kankan lati ọdọ rẹ''
''Ko si alaafia fun mi lati ọdun meje ti mo ti mọ ọ''
Ninu ọrọ rẹ, ọkọ iyawo Adebimpe ni oun fi ọwọ si ituka igbeyawo naa, amọ ohun ko jẹbi ẹsun ti o fi kan oun.
O ni igba de igba ni mo n fi owo ranṣẹ si Adebimpe, amọ mi o le gbe iru igbeaye olowo ti Adebimpe n gbe.
- Mo ṣetán láti dojú ìjà kọ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bá ọ̀rọ̀ ajé Eko jẹ́- Sanwo Olu
- Sanwo-Olu buwọ́lu ìgbésẹ̀ ìjọba láti tún Eko ṣe lẹ́yìn rògbòdìyàn EndSARS
- Bí àwọn kan tí ń ní àtimọ̀lé tí wọ́n sọ olorin Nazir sí ní Kano ni ọwọ́ kan òṣèlù ní àwọn mii ní...
- Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sílé aṣòfin ilẹ̀ Amẹrika
- Wo díẹ̀ lára àwọn gbajúmọ̀ òṣèré Yorùbá tó bẹ̀rẹ̀ eré ṣíṣe ní èwe.
















