Divorce in Nigeria: Abilékọ kan ṣàlàyé lórí ìdí tó fi gb'oyún láti ìta wá sọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ

Obinrin alaboyun

Oríṣun àwòrán, The Star

Abilekọ kan to n gbe ilu Ibadan, Toyin Bello ti sọ ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ, lori bi o ti gba ki ọkunrin mii fun un loyun lọọdẹ ọkọ rẹ.

Nigba to n jẹjọ nile ẹjọ kọkọ-kọkọ niluu Ibadan, Bello beere pe ki ileẹjọ tu igbeyawo ọdun mẹrindinlogun pẹlu ọkọ oun ka, nitori aileṣe bii ọkunrin rẹ.

Bello ti kọkọ fẹsun kan ọkọ rẹ pe, o fi Ibalopọ dun oun fun ọdun mẹwaa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Obinrin naa sọ fun ileẹjọ pe, oun gbe igbesẹ lati gb'oyún lati ita nitori itiju airọmọ bi.

Àkọlé fídíò, Èmi nìkàn kọ́ ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin

"Mi o fẹ ki oju ti ọkọ mi nitori airọmọbi lo jẹ ki n gba oyun lati ita," arabinrin Bello lo sọ bẹẹ.

Bello ni ọkọ oun tun fẹ ṣeku pa oun ko le jogun ile oun.

"Mo kuro nile lati maa gbe ni ṣọọṣi lagbegbe Asi n'Ibadan, Oluwa mi, mi o le maa fi akoko mi ṣofo mọ pẹlu Dotun, ọjọ ti n lọ lori mi. Ẹ jọwọ, ẹ tu igbeyawo yii ka," Bello rọ ileẹjọ.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Henry Agbaje to jẹ aarẹ ileẹjọ naa tu igbeyawo ọhun ka, o si pàṣẹ pe ki Dotun kuro ninu ile ti wọn jọ n gbe laarin ọjọ méje.

Amọ, Ọgbẹni Dotun tako idajọ naa, o si rọ ileẹjọ lati ba oun bẹ iyawo oun.

Dotun ni lootọọ ni pe oun ni ailera lati fun obinrin loyun, ṣugbọn iyawo oun naa ti ilẹkun mọ ri, ko jẹ ki oun wọle tọ ọ.