2021 Prophesies: Wòlíì Kolawole ní Ọlọ́run ló fi Makinde sípò, kìí ṣe àṣìṣe ní ìyànsípò rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Facebook/@OfficialSeyiMakinde
Ojisẹ Ọlọrun kan to fi ilu Ibadan se ibujoko, Wolii Richard Kolawole ti kede awọn iran nla to ri lori gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde.
Wolii Kolawole, lasiko to n sọ asọtẹlẹ rẹ fọdun 2021 tiwe iroyin Tribune gbe jade tun kede pe afaimọ ki aawọ nla to n waye laarin Makinde ati Ayodele Fayose ma doju ẹgbẹ oselu PDP bolẹ lorilẹede Naijiria.
Ojisẹ Ọlọrun naa ni yoo dara ki Makinde ati Fayose tete pe ara wọn joko lati yanju aawọ naa nitunbi n nubi, ko to pẹ ju, bi bẹẹ kọ, o le lẹyin bii oku iya jọjọ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àríyá oníhòhò àti ìbálòpọ̀ tó fẹ́ wáyé ní Kaduna lásìkò ọdún?
- Àjọ NIMC ti fún MTN, Glo, 9mobile àti Airtel ní àṣẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ fún NIN
- Wo iye àwọn ìpínlẹ̀ tó fòfin de ìsìn àìṣùn ọdún ní ṣọ́ọ̀ṣì
- Àwọn àjàkálẹ-àrùn tó ti wáyé rí ṣáájú Coronavirus
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn mẹ́ẹ̀dógún wọ gàù ọlọ́pàá ségí ní Eko
- Ikú Adewole Oniluola, tó ní ẹ̀bùn ìlù lílù jùlọ lágbàyéé, yóò nípa lórí Yorùbá - Tunde Kelani
Ko tan sibẹ o, Wolii naa tun ni awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP ti Seyi Makinde jade latinu rẹ ati ẹgbẹ oselu alatako, APC, ti n ditẹ nla mọ gomina naa.
O wa rọ awọn eeyan ipnilẹ Oyo lati tete kunlẹ adura fun gomina Seyi Makinde.
"Ọlọrun lo mọọmọ yan gomina Seyi Makinde lati dari ipinlẹ Oyo, kii si se asise lo fi de ipo naa. Amọ lọwọlọwọ bayii, wọn ti n ditẹ nla mọ.
Oluwa sọ pe iditẹ laagbara naa ko sẹyin ete lati yẹ aga gomina mọ Makinde nidi ninu ibo 2023, Oluwa ni yoo dara ko tete yanju isoro naa.
Mo wa n rọ gbogbo eeyan lati maa gbadura fun Seyi Makinde ko le ru re, ko si sọ re, nitori awọn eeyan to n ditẹ naa ti n leri-leka lati yẹ aga mọ nidi.
Yoo dara ki gomina Makinde to ile rẹ, ki awọn isoro yii lee di ohun itan saaju ọdun 2023.
Wolii Kolawole tun fikun pe ọwọja iwa ijinigbe yoo tubọ pọ si lorilẹede Naijiria ni 2023, ti isẹlẹ ẹkun omi pupọ ati ijamba ina yoo si waye ni ọpọ ipinlẹ.
O wa rọ awọn gomina ipinlẹ kọọkan lati san sokoto wọn ko le, ki wọn si setan lati koju awọn ipenija nla naa.
















