Passover Night: Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ní o lè gbàdúrà ìparí ọdún nílé rẹ láì lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì

Oríṣun àwòrán, CAC worldwide
Lílọ "Cross-over night" kò ní kí ọdún ó yabo láì ní ìpinnu tàbí ètò f'ọ́dún tuntun- Pásítọ̀ Ajifowowe
Cross-over night: Pásítọ̀ Ajifowowe ní "o lè gbàdúrà ìparí ọdún nílé rẹ láì lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì"
A ko gbọdọ tapa si ofin ijọba lori adura ipari ọdun 2020 si 2021 nitori ajakalẹ arun coronavirus.
Pasitọ Alfred Femi Ajifowowe lo sọrọ yii fun BBC Yoruba.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò fẹ́ kí ojú ti ọkọ mi, ni mo ṣe gbe oyún wá láti ìta - Abilékọ
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹlẹ̀ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọ́run tí kó ṣẹ́ lọ́dún 2020
- "APC àti PDP ń dìtẹ̀ láti yọ Seyi Makinde ní 2023, ẹ gbàdúra fun kó gúnlẹ̀ ayọ̀"
- EFCC gba ọ̀pọ̀ owó àti dúkìá, ó tún fọwọ́ òfin mú afurasí 865 lọ́dún 2020
- Ìwọ́de ńlá míì ń bọ̀ ní March, tí December 2021 yóò sì gbóná fáwọn ọ̀jẹ̀lú olóṣelú - Alfa sọ àsọtẹ́lẹ̀
- Njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àríyá oníhòhò àti ìbálòpọ̀ tó fẹ́ wáyé ní Kaduna lásìkò ọdún?
- Àjọ NIMC ti fún MTN, Glo, 9mobile àti Airtel ní àṣẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ fún NIN
- Wo iye àwọn ìpínlẹ̀ tó fòfin de ìsìn àìṣùn ọdún ní ṣọ́ọ̀ṣì
- Ikú Adewole Oniluola, tó ní ẹ̀bùn ìlù lílù jùlọ lágbàyéé, yóò nípa lórí Yorùbá - Tunde Kelani
Bẹẹ ba gbagbe, ijọba ipinlẹ Eko ti sọ tẹlẹ pe ẹnikẹni to ba tapa si ofin konile o gbele lati ago mejila oru si ago mẹrin owurọ, yoo sanwo itanran lati ẹgbẹrun lọna ogun naira sí ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira.
Nigba to n fesi si ọrọ yii, Pasitọ Ajifowowe sọ pe iwe mímọ ní kí a maa bọwọ fun awọn alaṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Pastor E.A. Adeboye
O ni "fun idi eyi, awọn Kristẹni ni lati gbọran, ki wọn si gbadura ipari ọdun yala nile wọn tabi ki wọn ṣe isin ipari ọdun ninu ṣọọṣi wọn ki o si pari si ago mọkanla dipo mejila to maa n pari tẹlẹ."
"Ni ṣọọṣi tiwa, ago mọkanla alẹ la o pari isin adura opin ọdun wa, ki awọn eeyan le lanfaani lati pada si ile wọn ki iṣede to bẹrẹ laago mejila."
Pasitọ Ajifowowe ni "lilọ si "Cross-over night" ko ni ki ọdun o yabo fun eeyan, bi ko ṣe ki eeyan ni ipinnu lori ọdun tuntun."
Pasitọ Ajifowowe ni ko sí ohun kan ti yoo yipada fun ẹnikẹni ti ko ba ni ipinnu tabi eto fun ọdun tuntun.
O ni ko si ohun to wa ninu "Cross-over night" ju kí eeyan fi ọna ara rẹ le Ọlọrun lọwọ ninu gbadura lọ.
Bakanna, olugbe ilu Eko ti ko darukọ ara rẹ sọ fún BBC Yoruba sọ pe, fun anfaani araalu ni ijọba ṣe sọ pe k'awọn eeyan gbe ile wọn lati ago mejila oru si ago mẹrin owurọ.
O ṣalaye siwaju síi pe Ọlọrun gan an lo fi awọn alaṣẹ ijọba sori oye, eyi to tumọ si pe "a gbọdọ gbọran sí wọn lẹnu."
Arabinrin naa tun sọ pe ko si bi awọn eeyan ko ṣe ni sun mọ ara wọn ju bo ti yẹ lọ ninu isin "Cross-over night."
Obinrin naa fikun ọrọ rẹ pe awon eeyan le ṣe isin ipari ọdun nile wọn lai lọ si ṣọọṣi.
Wo iye àwọn ìpínlẹ̀ tó fòfin de ìsìn àìṣùn ọdún ní ṣọ́ọ̀ṣì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi itankalẹ arun Covid-19 ṣe peleke si ni Naijiria, awọn gomina ipinlẹ kọọkan to fi mọ apapọ ẹgbẹ Kristẹni ni Naijiria wọgile ìsìn aisun ọdun tuntun, ti wọn maa ṣe lọdọọdun.
Asiko isin yii lawọn ile ìjọsìn máa n fi sadura ati ìsìn lati fi sure nkan daada ti wọn ba n fẹ lọdun tuntun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Njẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa àríyá oníhòhò àti ìbálòpọ̀ tó fẹ́ wáyé ní Kaduna lásìkò ọdún?
- Ìjà àgbà méjì! Àlàyé rèé lórí ááwọ̀ Femi Fani-Kayode àti Tunde Bakare
- Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn mẹ́ẹ̀dógún wọ gàù ọlọ́pàá ségí ní Eko
- Àwọn àjàkálẹ-àrùn tó ti wáyé rí ṣáájú Coronavirus
- Ta ni Ọ̀jọ̀gbọ́n àkọ́kọ́ nípa ìmọ̀ ọ̀daràn ní Nàíjíríà, Femi Odekunle tí Covid-19 pa?
- Ikú Adewole Oniluola, tó ní ẹ̀bùn ìlù lílù jùlọ lágbàyéé, yóò nípa lórí Yorùbá - Tunde Kelani
- Ayinla Ọmọwura, orin èébú àti oríyìn lo fi di ọ̀rẹ́ àwọ̀n obìnrin
- Ẹ wo ojú àwọn afurasí tí yóò rojọ́ ẹ̀ṣùn àjẹbánu lọ́dún 2021
- Bí Nàíjíríà bá fẹ́ kí ọdún 2021 dára, ohun tí yóò ṣe rèé - Obasanjo
- Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ méjì fìjà pẹẹ́ta, ẹ̀mí kan bọ́, ọ̀pọ̀ farapa
"Ìsìn oru ọdun tuntun "Cross over service" je ìsìn pàtàkì fawọn Kristẹni àti awọn musulumi kọọkan ṣugbọn nitori ajakalẹ Covid-19, ilana oriṣirisi ni wọn gbé kalẹ t'awọn mi sí wọgile ìsìn naa lodun yii.
Bawo ni ìsìn aisun ọdun lawọn ilẹ kaarọ oojiire?
Awọn ipinlẹ kan nilẹ kaarọ o jiire ti wọgile ìsìn yi patapata lọdọ wọn.
Ijọba Eko lo kọkọ wọgile ìsìn oru mojumọ naa, to sì ni awọn ṣe bẹẹ nitori aṣẹ ijọba apapọ lori isede ago mejila oru sí aagọ mẹrin afẹmọjumọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Pẹlu ilana tí ijọba gbe kalẹ yii, ọpọ àwọn ilé ìjọsìn n gbero lati ko idaji ọmọ ijọ wọn jọ lati ṣe ìsìn, ki gbedeke akoko isede to to.
Ni ipinlẹ Ogun, ijọba fòfin de ìsìn aisun ọdun tabi ipejọpọ kankan ni ipinle ọhun.
Amọ ṣa ẹgbẹ ọmọ Kristẹni ipinlẹ naa fẹ ki ijọba gbẹsẹ kuro lórí òfin yii.
Ijọba Oyo ko fi oju kekere mu ọrọ yii, ti wọn sì ti fohun silẹ pe awọn ko ni yẹ lori ipinu wiwọgile ijọsin aisun ọjọ ọdun.
Sugbọn iroyin to tun tẹ wa lọw nirọlẹ Ọjọru lo fi lede pe ìjọba Oyo naa tun ti pahunda, to si faaye gba awọn ile ijọsin lati se aisun ọdun.
Amọ o fi ote le pe awọn ọmọ igbimọ amusẹya lori Coronavirus yoo maa lọ yika awọn ile ijọsin naa lati ri pe ero to wa nibẹ ko ju aadọta lọ.
Nipinlẹ Ondo, Alaga tẹẹkoto lori kikoju Covid-19 ni ipinlẹ Ondo, Adesegun Fatusi ni, ko daa to ki olori awujọ tabi ẹsin maa kesi awọn eeyan lati tapa si ofin ijọba lori ọrọ ilera.
Ni ti ijọba ipinlẹ Osun, o ti kọkọ wọgile isin yii sugbọn wọn tun ipinu wọn da ro.
Kọmisana feto iroyin Funke Egbemode sọ pe, ijọba to n gbaroye araalu ni awọn jẹ, nitori naa, lawọn fi yi ipinu pada lori isin aisun ọjọ ọdun tawọn wọgile saaju.
O sọ pe "Ijọba Osun ti pinu lati jẹ ki awọn eeyan korajọ fun isin yii sugbọn ile ijọsin ti yoo ba se isin gbọdọ ri pe awọn eeyan pari rẹ lasiko, ti wọn ko si ni kọja aago kan oru''
Isin Cross over ori ayelujara:
Ijọ RCCG (Redeemed)
Ohun ti ile ijọsin Redeemed Christian Church sọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ ni pe lori ayelujara lawọn yoo ti se isin tọdun aisun dun tawọn.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita, wọn ni eyi wa lati bọwọ fun ilana tawọn ijọba apapọ ati ipinlẹ gbe jade nitori itankalẹ Covid-19.
Winners Chapel:
Bakan naa ni ijọ Winners Chapel ti kọkọ kede pe isin aisun ọdun ko ni waye ni gbogbo ẹka ijọ naasutgbọn nigba to ya, lo tun da ọrọ rẹ ro, to si ni isin naa yoo waye pẹlu awọn ilana kan.
Bo ti lẹ jẹ wi pe oludasilẹ ijọ naa ti saaju bẹnu atẹ lu idena akojọpọ ijọsin, amọ Bisọọbu David Oyedepo ni oun yi ipinu pada nitori isin tawọn maa n se kii kọja ago mẹwa si ago mẹrin owurọ ni gbogbo ọjọ Kọkanlelọgbọn osu Kejila ọdọọdun.
O ni dipo isin oru ọjọ ọdun, awọn yoo se isin lọjọbọ ti yoo gba awọn ni nkan bi wakati meji si mẹta, ati pe, lọjọ ọdun awọn yoo se isin kan laago meje aarọ, tawọn yoo si fi han lori ayelujara.
Mountain of Fire:
Bẹẹ naa ni oludasilẹ ijọ Mountain of Fire and Miracles Ministry, sọ pe ijọsin awọn yoo waye laarin ago mẹsan si mọkanla. O ni eyi to ku awọn yoo maa se lori ayelujara titi wọ ọjọ ọdun.
Deeper Life:
Ni ti ijọ Deeper, awọn sọ pe ago mẹwa alẹ lawọn yoo bẹrẹ isin aisun ọdun tuntun.
Covenant Christian Centre to wa ni Eko sọ pe awọn eeyan yoo kopa ninu isin awọn laarin ago meje alẹ si ago mẹsan alẹ.Amọ eyi to ku awọn yoo se loju opo ayelujara lati ago mọkanla alẹ di ago kan owurọ.
Ajọ CAN pẹlu pa ohun rẹ da:
CAN ti saaju sọ fun BBC pe awọn ko mọ nkankan nipa ilana ti ijọba gbe kalẹ lori isin oru aisun ọdun sugbọn wọn yi ohun pada ninu atẹjade kan.
Aarẹ CAN Samson Ayokunle sọ fun gbogbo awọn ile ijọsin Naijiria lati bọwọ fun ofin ki wọn si tẹle ilana ijọba nipa isin ọjọ aisun ọdun.
Wọn ni ko si ''ifarajin to pọju lati wa ọna idẹkun ajakalẹ yi patapaa''
CAN wa parọwa sawọn ile ijọsin gbogbo nipinlẹ ti ijọba ti wọgileisin yi lati se isin wọn ki ọjọ to lọ ki wọn si palẹmọ o pẹ ju ago mọkanla alẹ.
Kí ló dé tó jẹ́ sọ́ọ̀sì nìkàn ni ìjọba ń tìlẹ̀kùn mọ́ torí Covid-19? - CAN

Oríṣun àwòrán, Catholic Church of Nigeria
Ẹgbẹ́ ọmọlẹ́yìn Kírístì ni Nàìjíríà (CAN) ti rọ àwọn ìjọ ni gbogbo ìpinlẹ̀ Nàìjíríà, tó fi mọ ìlú Abuja, láti tẹ̀lé gbogbo ìlànà ìjọba lórí ọ̀rọ̀ Covid-19.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, àgbẹnusọ ààrẹ CAN, Pásítọ̀ Bayo Oladeji tó sọ̀rọ̀ lórúkọ ààrẹ ẹgbẹ́, Dókítà Supo Ayokunle ni, gbogbo àwọn alága ìpínlẹ̀ ni àwọn ti jọ sọ̀rọ̀ yé pọ láti tẹ̀lé òfin ti ìjọba ìpínlẹ̀ ti wọ́n wà bá là sílẹ̀ lori sise aisun ọdun tuntun.
Oladeji ní gẹ́gẹ́ bi ìròyìn tó tẹ́ ẹgbẹ́ CAN àpapọ̀ lọ́wọ́, ìjọba apapọ̀ kò fi ìgbà kankan sọ pé ki àwọn ìjọ máse péjú fún ètò ìsìn ìrékọjá sínú ọdún tuntun, sùgbọ́n àwọn ìpińlẹ̀ kan sọ pé, lá kò sí ǹkan tó jọ ọ́.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ wo àwọn ìlúmọ̀ọ́ká ọmọ Nàíjíríà tó jáde láyé lọ́dún 2020
- Ìtàn ìgbé ayé Isola Ogunsola, akọni mánigbàgbé òṣèré tíátà, olórin àti onílù
- Aráàlú dá iná sun èèyàn méjì n‘Ibadan, orí kó ẹni kan yọ
- "Ma a pa ara mi si Cute Abiola lọrun bo ṣe já mi silẹ tori afẹsọna miran"
- "Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àgbà fipá bá ọmọkùnrin mi lòpọ̀ níléèwé Deeper Life, mò ń fẹ́ ìdájọ́"
- Kí ló fa gbas-gbos láàrín Davido àti Burna boy lórílẹ̀èdè Ghana?
- Wo ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ igba tí Primate Ayodele gbé síta fọ́dún 2021
Gẹ́gẹ́ bí ìgbésẹ̀ tí àjọ CAN ń gbé, àwọn yóò fi àtẹjáde kan síta lónìí ọjọ́ ìṣẹ́gún láti sọ fún gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti tẹ̀lé ǹkan ti ìjọba ìpínlẹ̀ wọ́n bá sọ.

Oríṣun àwòrán, Ayokunle
Oladeji sàlàye pé, ó ṣeni láànu pé, sọ́ọ̀sì nìkan ni ìjọba n kọjú sí lórí títèlé àlàálẹ̀ òfin Covid-19, bí ó ti lẹ̀ jẹ́ pé gbogbo òfin yìí ni àwọn ìjọ ń tẹ̀lé.
"Tí ẹ bá lọ sínú àwọn ọjà wa, kò sí ẹni tọ n tèlé ìlàna òfin Covid-19, ko si si ẹni tó mú wọ́n si.
Kódà gbogbo àwọn olóṣèlú wa ni à n ri lóri amóhùnmáwòràn bi wọ́n ṣe n ṣe ètò òṣèlú láì tẹ̀lé òfin Covid-19 sùgbọ́n tó bá ti di ọ̀rọ̀ sọ̀ọ́sì..."
Bákan náà lo rọ àwọn ìjọ pé, ki wọ́n fi alafo tó péye silẹ̀ dáada láàrín àwọn ara sọ́ọ̀sì ki wọ́n ma ba fún pọ́.
Ó tún ni àwọn rọ wọ́n kí wọ́n ṣe ìsìrìn náà sáájú àsìkò tí wọ́n maa n ṣee tẹ́lẹ̀ ki olúkúlùkù sì pàda síé wọ́n kí ilẹ̀ tó ṣú.
"Gbogbo ǹkan ti ìjọba n ṣe yìí fún ànfàní olúkúlùkù ni, nítórí náà gbogbo ǹkan ti a bá le ṣe, láti dẹ́kun àjàkálẹ̀ ààrùn Covid-19 ki ó fi kásẹ̀ nílẹ̀, ni à ó ṣe".
"Tí a bá ti ṣe, ti àìsàn yìí bá ti lọ pátápátá, à ó pada si bí a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀".
Bákan náà ló tun rọ àwọn ìjọ tó ni onírúúrú ààyè nínu ilé ìjọsin wọ́n, pé ki wọ́n pin àwọn ènìyàn síbẹ̀ tàbi kí wọ́n pín ìsì wọ́n sí ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ, ki èrò má ba pọ nínú ìsìn.
Sáájú àsìkò yìí ni ẹ̀ka CAN ti ìpínlẹ̀ Ondo ti ni, kò sí ǹkan tó kan àwọn pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìjọba nítórí náà àwọn yóò ṣe ìsìn òpin ọdún ní tàwọ́n.
















