2021 Prophecies: Olagoke ní ẹni tó bá fi ara rẹ̀ sílẹ̀ fún Ọlọ́run, yóò ríran

Sabitu Ariyo Olagoke

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ariyo Olagoke

Asọtẹlẹ ọdun 2021 ti onimọ nipa ẹsin Islam, Sheik Sabitu Ariyo Olagoke sọ, eyi ti BBC gbe jade ti n fa oniruuru auyewuye lori ayelujara.

Olagoke lọjọ aisun ọdun tuntun lo kede nipa awọn isẹlẹ alagbara ti yoo waye lọdun tuntun, ninu eyi to ti sọ pe iwọde miran to ju ti Endsars lọ tun n bọ losu kẹta ọdun 2021.

Sugbọn awọn asọtẹlẹ yii ni awọn ọmọ Naijiria kan, paapaa awọn musulumi tako pe ko ba ilana ẹsin Islam mu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu alaye awọn eeyan to fesi si asọtẹlẹ ti onimọ yii gbe kalẹ, wọn ni esin Islam ko faye gba ki eeyan maa sọ asọtẹlẹ nitori ko si ẹni to ni imọ ikọkọ.

Ariwisi araalu

Oniruuru awọn ọrọ kobakungbe ni wọn n sọ nipa awọn asọtẹlẹ naa, eyi to n kọ ọpọ eeyan lominu.

Idi ree ti BBC Yoruba se ba Sheik Olagoke sọrọ lati mọ boya lootọ ni iwa sisọ asọtẹlẹ ko si ninu ẹsin Islam.

Ninu ifọrọwerọ rẹ, Olagoke ni ''Alainimọ ẹsin Islam lo maa sọ wi pe ẹsin ko faye gba ki eeyan maa sọ asọtẹlẹ''

Ojisẹ Ọlọrun naa, to tako ero awọn eeyan to ni ko si asọtẹlẹ ninu Islam, tun salaye pe ''Bi ẹ ba wo inu Kurani ninu Surah Kẹtadinlọgọta (57) ẹsẹ Kejilelogun si ikẹtalelogun(22 -23), ko si isẹlẹ to n waye ninu aye, inu ẹmi la a kọkọ gbe si''

Ẹsẹ Alukurani

Surah ti ọjọgbọn yi n sọ nigba ti a sagbeyẹwo rẹ jẹ Surah Hadid, to si sọ ọrọ nipa pe ko si nkankan ti yoo sẹlẹ si ẹda ọmọniyan ni aburu, ti kii se pe o ti wa ninu akọsilẹ lọdọ Ọlọrun(Allah).

Surah naa tẹsiwaju pe, o rọrun fun Ọlọrun (Allah) lati sọ di imusẹ sugbọn ko sọ nipa pe eeyan le mọ nkan to wa ninu akọsilẹ yii tabi ko le sọ di imusẹ fawọn eeyan.

Ọjọgbọn Sabitu salaye siwaju pe ''Aanu ati ibukun ni ki eeyan le riran, sugbọn ọpọ awọn to ni ẹbun yii, n se ni wọn fi n sofo''

Àkọlé fídíò, Èmi nìkàn kọ́ ni mó n ṣe àkójọ orin- Fasoyin

O fi kun pe ''ẹni to ba fi ara rẹ silẹ to si n gbọ bi Ọlọrun ti se n ba sọrọ yala ninu Kurani ni tabi ninu bibeeli, iru eeyan bẹẹ yoo si ma riran.''

''Awọn to n sọ́ wi pe ko tọna, wọn ti ju ara wọn silẹ, a ko le ran wọn nisẹ, awọn ni wọn n ran ara wọn nisẹ.''

Ojọgbọn naa wa fidi rẹ mulẹ pe, nkan meji ni kii mu asọtẹlẹ di mimu sẹ lode oni.

Akọkọ alaye to se ni pe, ki awọn eeyan maa mu ifẹ inu ti wọn wọ inu asọtẹlẹ tabi ọna ati ri owo gba.

Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

''Bi a ba fi iran se inunibini si ijọba kan, ka sọ wi pe ijọba rẹ yoo kogba wọle lọla, iru nkan bayi kii mu ki asọtẹlẹ di imusẹ.

Ẹlẹẹkeeji to ni kii mu ki asọtẹlẹ di mimu sẹ ni ki awọn eeyan kan gbọ asọtẹlẹ, ki wọn ma sisẹ tọ imusẹ asọtẹlẹ ọhun.

Ìwọ́de ńlá míì ń bọ̀ ní March, tí December 2021 yóò sì gbóná fáwọn ọ̀jẹ̀lú olóṣelú - Alfa sọ àsọtẹ́lẹ̀

Professor Sabit Ariyo Olagoke

Oríṣun àwòrán, Professor Sabit Ariyo Olagoke

Saaju la ti kọkọ mu iroyin wa fun yin pe onimọ nipa ẹsin Islam, Ọjọgbọn Sabitu Ariyo Olagoke ti gba awọn ọmọ Naijiria nimọran lati mase bẹru aṣọtẹlẹ, nitori yoo palẹ ọkan wọn mọ fun bi ọdun tuntun yoo ṣe ri ni.

Sabitu Ariyo Olagoke ni ki orilẹede Naijiria ba le e tẹsiwaju ni ọdun 2021, awọn ẹlẹsin gbọdọ fi ọwọ sowọpọ lati mu alafia jọba ni agbegbe wọn.

Alfa Olagoke wa kilọ fun awọn eniyan lati maṣe fi oju di arun Coronavirus nitori yoo mu ọpọ ẹmi lọ, ti wọn ko ba tẹle awọn ofin to rọ mọ didẹkun itankalẹ arun naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Onimọ ẹsin Islam naa, ẹni to pe akori asọtẹlẹ rẹ ni "What 2021 has in store for Nigeria", kede awọn ọrọ naa lati mọsalasi Shafaudeen In Islam Worldwide ni Wakajaye Ibadan.

Lara awọn asọtẹlẹ naa ree:

  • Ninu ọdun 2021, eto aabo yoo tunbọ dẹnukọlẹ si paapaa ni Osu Keji nitori naa awọn adari ẹsọ alaabo gbọdọ mura si ọrọ eto abo ni Naijiria
  • Ni Osu Kẹta, ọdun 2021, awọn eniyan yoo tun bẹrẹ si ni ṣe ifẹhọnuhan tako ijọba, ti ọpọlọpọ awọn oloṣelu yoo si tako ara wọn, ti wọn yoo si gbe igigisẹ si ara wọn
  • Alfa Olagoke ni eto ẹkọ yoo ru gọgọ si ni ọdun 2021, ti igbelarugẹ yoo si ba eto ẹkọ, nitori naa Oṣu Kẹjọ ọdun naa yoo mu aṣeyọri ba eto ẹkọ ni Naijiria
  • Amọ, Oṣu Kejila, ọdun 2021 yoo gbona fun awọn ọjẹlu to ṣebi oloṣelu ati awọn ọmọ wọn
  • Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ to yẹ ki wọn fẹyinti, ti wọn kọ naa ni wọn yoo wa jade, ti asiri wọn yoo si tu
  • Osu Kọkanla, ọdun 2021 yoo jẹ osu rere fun awọn ọmọ Naijiria, nitori idẹrun yoo de fun awọn ọmọ Naijiria to ba n ṣe rere.
Àkọlé fídíò, Alapinni Oosa ṣàdúrà fún gogbo ọmọ kúoótù, oò jíire bí?

Onimọ nipa ẹsin Islam, Ọjọgbọn Sabit Ariyo Olagoke naa wa rọ ijọba lati mu ọrọ eto aabo lọkunkundun, ki o ma ba da wahala silẹ ni ọdun tuntun.

Bakan naa ni Alfa naa rọ ijọba ati ẹgbẹ awọn olukọ Fasiti lati ṣe ojuṣe wọn, ki eto ẹkọ le tẹsiwaju, ki awọn ọdọ ma ba a tọwọ bọ iwa ọdaran.