Cancer Marriage: Oṣù kan péré ni Tash fi ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Simon kó tó kú
Yoruba ni airin jinna ni airi abuke ọkẹrẹ, bii eeyan ba rin jinna, yoo ri ibi ti wọn ti n fi odo ibulẹ jẹun.
Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu tọkọ-taya kan, Tash ati Simon Young, ti wọn se igbeyawo nile iwosan nigba ti dokita ni arun jẹjẹrẹ to n se iyawo, ko ni pẹ mu ẹmi rẹ lọ.
Nigba to n ba BBC srọ, Simon ni osu kan pere ni oun ati aya oun, Tash, fi se igbeyawo ko to dagbere faye, ọjọ mẹrin pere si ni awọn fi palẹmọ fun igbeyawo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ṣo mọ̀ pé J.F Odunjo jẹ aṣòfin àti mínísítà nílẹ̀ yìí, yàtọ̀ sí pé ó jẹ́ òǹkọ̀wé?
- Ó pé ọdún mẹ́rìnlélàádọ̀ta tí Akintola kú, ìdí abájọ ìja rẹ̀ pẹ̀lú Awolowo rè é
- Ìtàn Gbọnka àti Timi, akọni méjì tó borí Aláàfin Ṣango
- Òkè Idanre rèé tí odidi ìlú kan ló ń gbé lórí ẹ̀
- Eji Gbadero, ọmọ Ibadan àti jayé-jayé ọmọ ónílẹ̀ ti wọn yẹgi fun l'Eko
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
Simon ni ọjọ igbeyawo naa ni inu oun dun julọ, paapaa, nigba ti oun n wo aya oun bo se n rin ati bo se n rẹrin musẹ.
Fidio yii, koseemawo ni, ninu rẹ naa lẹ ti gbọ ohun ti awọn dokita atawọn ẹbi iyawo sọ nipa obinrin naa ati ọrọ ifẹ Tash ati Simon Young.