Bisi Alimi: Inú mi dùn sí bí Gabon ṣe fòǹtẹ̀ lu òfin pé kí akọ máa fẹ́ akọ
Ilumọọka akọ kan to nifẹ si akọ ẹgbẹ rẹ, Bisi Alimi ti ni idunnu lo jẹ fun oun lati ri pe orilẹede Gabon ti se ohun to yẹ ki wọn se, lori fifi ọwọ si ofin pe ki akọ maa fẹ akọ.
Alimi, to fẹ akọ ẹgbẹ rẹ ni ọkọ tun sisọ loju rẹ pe, ọpọ awọn akọ to n fẹ akọ ati abo to n fẹ abo lo nifẹ ohun ti orilẹede Gabon se yii, amọ iha ti Naijiria kọ si igbesẹ naa n ba oun ninu jẹ.
- "Ọkùnrin ẹgbẹ́ mi ni mo fẹ́ níyàwó, mo nífẹ̀ẹ́ bí ẹlẹ́dàá ṣe dá mi"
- Tẹgbọn-taburo se igbeyawo ni Anambra
- Àwọn nǹkan tí obìnrin lè ṣe pẹ̀lú olólùfẹ́ oníwà ipá lásìkò ìgbélé Coronavirus yìí
- Ọkọ'yàwó jẹ àjẹranjú ìyà lẹ́yìn tí ìyàwò rẹ̀ yọjú síbi ìgbéyàwó òun àti obìnrin mìràn
- Iléẹjọ́ wọ́gilé ìgbeyàwó nílànà ẹ̀sìn Islam pé kò bófin mu
- Iwa nabi tu igbeyawo ọgbọn ọdun ka
Bisi Alimi fikun pe, asa Yoruba ko lodi si pe ki akọ nifẹ si akọ ati abo ni ifẹ si abo lati ba se igbeyawo amọ koko to wa ninu asa Yoruba ni ka ni ifẹ si ara wa, nitori ifẹ ni akoja ofin.
O wa fi Oriṣa Sango se apẹẹrẹ bi Yoruba se faramọ iwa ki ọkunrin maa mura bi obinrin nitori Sango n di irun, o n wọ asọ obinrin, to si tun n lo yẹti.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Alaafin, MC Oluomo, Ejiogbe àti ọmọ Tinubu wà lára àwọn tí yóò pèsè iṣẹ́ 774,000
- Baba Suwe bọ́ lọ́wọ́ àìsàn, ó bẹ̀rẹ̀ tíátà padà
- Jàndùkú yabo ilé ìwòsàn ìjọba sáájú ìpàdé akọ̀ròyìn táwọn dókítà pè
- Ojú Shagbada Erigga rèé lẹ́yìn tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ l'Akinyele ní Ibadan
- Ìdí tí lílọ Yúrópùù fi di èèwọ̀ fún Nàìjíríà àti àwọn orílẹ̀-èdè adúláwọ̀ míì
- Arúfin ni Seyi Makinde pẹ̀lú bó ṣe gbà kí wọ́n sin Ajimobi sí GRA - Amòfin
Alimi wa koro oju si awọn oloselu lori bi wọn se n dẹyin si awọn akọ to n fẹ akọ ati abo to n fẹ abo, to si ni ko yẹ ki eyi ri bẹẹ nitori gbogbo wọn lo jọ dibo fun awọn oloselu yii.