Fani-Kayode Defection to APC: Salihu ní dípò ayọ̀, ẹ̀hónú ni ìpadàbọ̀ mínísítà náà mú lọ́wọ́ nínú APC

Femi Fani-Kayode ati Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Femi Fani-Kayode Facebook

Bi Ọgbẹni Femi Fani-Kayọde se kuro lẹgbẹ oselu PDP, to si darapọ mọ APC ti n fa awuyewuye laarin ẹgbẹ oṣelu APC naa to lọ darapọ mọ.

Amọ dipo ariwo ayọ to yẹ ki ipadabọ rẹ si agbo APC mu wa, ẹhonu ati rogbodiyan lo mu lọwọ, eyi ko si ṣẹyin oju ti wọn fi wo iwa rẹ lagbo oṣẹlu ati bi aja rẹ ko ṣe mọ pe ẹnikan la kii gbo mọ.

Oludari agba fajọ awọn gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC, PGF, Ọmọwe Salihu Lukman, lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan to fisita niluu Abuja lọjọ Aiku.

O ni gbogbo eeyan lo mọ pe a kii ṣọrẹ ero ka yọ lọrọ Fani-Kayode, ko si mọ bi a ṣe n ba ẹnikẹni ṣe ọrẹ fun igba pipẹ yala lagbo oṣelu ni o tabi lẹka miran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni lati igba ti iroyin yii si ti jade, ko fẹrẹ si ẹnikan to tii sọrọ rere nipa igbesẹ naa biotilẹjẹpe irufẹ idarapọ bayii yẹ ko mu ọpọlọpọ ariwo ayọ dani.

O ni lara awọn to koko tako igbawọle Fani-Kayọde s'ẹgbẹ oṣelu APC ni amugbalẹgbẹ fun aarẹ Buhari lori ọrọ oṣelu, Sẹnetọ Babafẹmu Ojudu, to ṣalaye pe ọjọ to ba oun ninu jẹ julọ ninu irinajo oṣelu oun ni ọjọ ti Fani-Kayọde darapọ mọ APC naa.

Àkọlé fídíò, Sabaa Akintola: Pẹ̀lú ẹsẹ̀ kan, mo le gun kẹ̀kẹ́, lúwẹ̀ẹ́ tàbí rán aṣọ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ dókítà

Ọmọwe Lukman ni ko fẹẹ si eekan APC kankan ti inu rẹ dun si bi awọn alagbara kan ṣe mu Fani wọ ẹgbẹ oṣelu naa, ṣugbọn niwọn igba to ti ṣẹlẹ ko si idi mọ lati maa pariwo lori rẹ nitori ohun ti yoo ṣe ti ṣe atipe aarẹ funrararẹ ti dariji i.

O ni pẹlu gbogbo ohun buruku ti Fẹmi Fani-Kayọde ti sọ nipa ẹgbẹ oṣelu APC atawọn aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu naa sẹyin, yo ba ṣeeṣe fun awọn asiwaju ẹgbẹ naa lati dariji ko si idi fun ọmọ ẹgbẹ naa lati tun ṣi maa fapa janu lori rẹ.

"Awọn ọmọ ẹgbẹ ni lati fiyedenu ni" lọrọ ti oludari agba ajọ awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọwe Ridean Lukman sọ

O fi kun un pelati ọdun 2015 si asiko ti a wa yii, ọpọlọpọ awọn oloṣelu lo ti darapọ mọ APC ṣugbọn to jẹ pe wọn pada dalẹ ẹgbẹ oṣelu naa ni eyi to ni o mu ki inu maa bi awọn ọmọ ẹgbẹ pupọ wọn si n woye pe awọn eeyan ti ko ṣe finu tan ni wọn n ko wọnu ẹgbẹ naa.

O ni ko yẹ ki ọrọ Fani-Kayọde o da omi tutu sawọn ọmọ ẹgbẹ lọkan, gbogbo ọmọ ẹgbẹ APC lo si yẹ ko mọ pe ajọṣepọ wọn, ati atilẹyin wọn lo mu ẹgbẹ oṣelu naa goke agba de ibi to de bayii.

Amin iyasọtọ kan

"Buhari, to bá fún Fani-Kayode ní ipò, àwa ọ̀dọ́ yóò fí ẹ̀họ́nú hàn"

Femi Fani-Kayode

Oríṣun àwòrán, Facebook/Femi Fani-Kayode

Eekan kan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Ben Adaji ti ṣeleri pe, ohun yoo ṣe agbatẹru fun awọn ọdọ kaakiri orilẹede Naijiria lati ṣe iwọde, ti aarẹ Buhari ba fun Femi Fani Kayode ni ipo ni ijọba rẹ.

Ben Adaji sọ eyi lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ ni ilu Jalingo ni ipinlẹ Taraba.

O wa kilọ fun awọn alaṣẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC lati ṣọra gidigidi fun Fani-Kayode to jẹ minisita tẹlẹri fun ọrọ oju ofurufu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni ọdalẹ eniyan lati igba de igba ni Fani-Kayode, ki wọn si ṣọra fun un.

Adaji ni o ṣoro lati fi ọkan tan Fani-Kayode to kuro ni ẹgbẹ oṣelu APC ni ọdun 2014 lọ si ẹgbẹ oṣelu PDP, lẹyin to ṣe apejuwe aarẹ Buhari pe o n sa gbogbo ipa rẹ lati sọ Naijiria di orilẹede awọn Musulumi nikan.

Àkọlé fídíò, Ayo Ewebiyi Mama Oriki: Ọwọ́ Òbí, Ìjọba àti àwọn Ọba ni ìdágbàsókè Yorùbá wà lásìkò yìí

O ni Fani-Kayode sọ nigba naa pe aarẹ Buhari ni ero lati fi iya jẹ awọn ọmọ Naijiria lasiko iṣejọba rẹ.

Bakan naa lo fikun pe Fani Kayode lati ọdun 2014 lo ti n sọrọ aarẹ Buhari ni aida pẹlu awọn ọrọ kubakugbe to ma n sọ si aarẹ lori ẹrọ ayelujara.

Eekan ni ẹgbẹ oṣelu APC, Ben Adaji wa rọ aarẹ Buhari ko tun ero rẹ pa nigba Fani-Kayode.

Adaji ni kio aarẹ Buhari kọkọ wo awọn ti wọn duro ti wọn si satilẹyin fun ẹgbẹ naa lati fun wọn ni ipo, ki wọn to lọ si ọdọ iru eniyan bi Fani-Kayode.

Ọpọlọpọ eniyan lo ti bu ẹnu atẹ lu bi Fani-Kayode ṣe pada si ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin ọrọ kubakugbe to si sọ nipa ẹgbẹ oṣelu naa ati aarẹ Muhammadu Buhari.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn