Mike Bamiloye pá àrokò ìkìlọ ránṣẹ sí àwọn ọkùnrin Nàìjíríà lórí àgbèrè ṣíṣe

Oríṣun àwòrán, Mount Zion
Ẹyin ọkunrin Naijiiria, ẹ jawọ nibi piparọ obinrin bi ẹni parọ aṣọ.
Gbajugbaja oṣere ẹlẹsin Kristẹni ajihinrere Mike Bamiloye lo n parọwa bayi sawọn ọkunrin lati sinmi piparọ obinrin bi ẹni parọ '' handkerchief''
Ninu ọrọ to fi si oju opo rẹ ni Instagram lo ti gbawọn ni amọran yi.
- Eré ìfẹ́ di eré ẹkún! Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò tí wọ́n n bá ara wọn sùn nínú adágún odò
- Àwọn agbẹ́bọn tí pa alága ẹgbẹ́ Miyetti Allah tí wọ́n jígbé ní Kaduna- Miyetti Allah
- Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun ti pàsẹ pé ki adarí OPIC tẹ́lẹ̀ri dá #40 miliọ̀nù padà
- Ọjọ́ tò burú jùlọ nínú ìrìnàjò oṣèlú mi ni ọjọ ti FFK darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC- Ojudu
Bamiloye ti ọpọ mọ fun ere ori itage ''Agbara nla'' ni lati ibẹrẹpẹpẹ lo ti yẹ ki awọn ọkunrin mojuto ibaṣepọ wọn pẹlu awọn obinrin.
O ṣakawe lati inu iwe bibeeli bi Samson ti ṣe ṣaṣiṣe nipasẹ iyawo to yan ati awọn obinrin miran to ni ajọṣepọ pẹlu.
O kesi awọn ọdọ iwoyi pe ki wọn ma ṣe fi obinrin ta tẹtẹ nitori ọrọ yi kii ṣe ọrọ awada rara.
- Ọ̀rẹ́ wa ni Lawrence jẹ́, àmọ́ ó gbẹ̀yìn dẹ́nu ìfẹ́ kọ abúrò wa - Joshua àti Damilola Bamiloye
- Ìwọ tó ń ṣí ara sílẹ̀ lọ ṣọ́ọ̀ṣì, ṣé apàyàn kọ́ ni ẹ́ báyìí?- Mike Bamiloye
- Fíìmù India tó gbé agbára oṣó àti àjẹ́ ga ló mú kí ń gbaná jẹ fún Jésù láti ṣe sinimá - Mike Bamiloye
- Ẹ ṣeun, ẹ kú àdúrótì mi! Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí Tope Alabi padà sọ nípa awuyewuye tó wáyé lóri orin Oniduro Mi
O ni bi wọn ba ri piparọ obinrin gẹgẹ bi nkan igbadun adanu ni ytoo gbẹyin rẹ fun wọn.
''Ẹ bi Solomon,ẹ bi Samson, ẹ bi Judah ati Tamar, ko si ọkunrin to moribọ ninu ere gele pẹlu obinrin''

Oríṣun àwòrán, Instagram/mikebamiloye
O gba awọn ọdọkunrin ni amọran pe ti wọn ba fẹ ṣe amuṣẹ ileri Ọlọrun ninu aye wọn, ki wọn ya tete ri pe wọn fẹ iyawo to dara.












