OPIC: Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun ti pasẹ ki adarí OPIC tẹ́lẹ̀rí dá #40 miliọ̀nù pada

Ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun ti pasẹ ki adarí OPIC tẹ́lẹ̀rí láti dá #40 miliọ̀nù pada

Oríṣun àwòrán, Ogun

Ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ogun ti pàsẹ fun adarí ilé iṣẹ to n ri si okoòwò ati nǹkan ìní (OPIC) ọ̀gbẹni Babajide Odusolu láti da ogójì mílíọ̀nu ti ko le ṣàlàyé owó fun ọdún 2019 laarin oṣù mẹ́fà.

Èyí ni àfẹnukò ilé lásìkò ìjòkó ilé, abẹnugan ile Olakunle Oluomo ni Abeokuta lọjọ Eti lẹ̀yín ti wọ́n gba abá ìgbìmọ̀ tẹẹkoto lori iwe owo ijọba ati ìwa jẹgudujẹra ti Musefiu Lamidi n dari.

Lamidi lásìkò to n jábọ, sọ pe ìgbìmọ̀ naa ti yẹ iwe owo wọ lati ọdun 2015 titi di ọdun 2019.

Lamidi sọ bákan náà pé ki wọn gba aba naa wọlé ti Oludaisi Elemide si kin lẹyin ti gbogbo ile naa si gbàá abajade igbimọ ọhun wọlé pẹ̀lú ohùn wọn.

Àkọlé fídíò, Akomolede: Akuko Gagara ni ìwé tó ṣàfìhàn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Nàìjíríà lásìkò yìí- Fatimo B

Bákan náà ni wọn pe àjọ tó ń ri si ìwà jẹgúdújẹrá (EFCC) láti ṣe ìwádìí ọkùnrin naa ati lati wo apo owo ijọba lati mọ ibi ti biliọnu meji abọ naira wọlẹ si lasiko idari rẹ nile iṣẹ.

Àkọlé fídíò, Ayo Ewebiyi Mama Oriki: Ọwọ́ Òbí, Ìjọba àti àwọn Ọba ni ìdágbàsókè Yorùbá wà lásìkò yìí

Igbimọ naa tun daba pe ki wọn da gbogbo eto owo ti wọn ti se pada to fi mọ tita Heeka ilẹ mejọ ti wọn ta ni Iseri fun ile isẹ Rainerhill International ni mílíọnù tó le diẹ ni aadọ́jọ.

Àkọlé fídíò, Jẹ́ ká lọ sílu mi: Kò sí ìtàn Ibadan láìsí Efunsetan, Òkè méje, Bower's Tower àtàwọn ǹkan

Igbimọ naa ni gbogbo nkan ti awọn n se wa fun anfani ara ilu nitori naa gbogbo iwe ti wọn ti gbe fun ile isẹ Rainerhill nitori ilẹ ti wọn ra ni o ti di ofo nigba ti ipinlẹ Ogun lo si ni ilẹ naa.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

Bakan naa igbimọ naa tun ni ki ijọba fi ofin de gbogbo banki mẹrindinlogun ti ile iṣẹ naa n kowo si.

Àkọlé fídíò, Oloye Peter Fatomilola: Ọjọ̀gbọ́n olùkọ́ni ni Jesu àti Orunmila jẹ́, àwòkọ́ṣe sí rere si n