FG vs resident doctors: Ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn ni yóò parí ọ̀rọ̀ yìí -Ẹgbẹ́ àwọn Dókítà Naijiria

FG vs resident doctors: Ilé ẹjọ́ kò tẹ́milọ́rùn ni yóò parí ọ̀rọ̀ yìí-Ẹgbẹ́ àwọn dókítà

Oríṣun àwòrán, NARD

Ẹgbẹ awọn dokita ti fesi si aṣẹ ti ile ẹjọ pa lọsan ọjọ Ẹti pe ki wọn pada sí ẹnu iṣẹ wọn ki wọ́n si pada lọ se ipade pẹlu ijọba lórí ẹ̀hónú wọn.

Wọn ni awọn ti ṣetan lati gbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ ko tẹmi lọrun, ẹgbẹ awọn dokita ni awọn ti jẹ ki agbẹjọro ẹgbẹ naa mọ pe awọn yoo pe idajọ ile ẹjọ nija lati lọ si ile ẹjọ kotémilọrun ati pe ọmọ ẹgbẹ kankan ko ni pada si ẹnu isẹ.

Ikede yii waye ninu atẹjade kan ti aarẹ awọn ọmọ ẹgbẹ dokita Dokita Uyilawa Okhuaihesuyi ati akọwe ẹgbẹ naa Dokita Jerry Isogun jùmọ̀ fọwọ si lonii.

O ni awọn ti bẹrẹ igbesẹ gbigbe ẹjọ naa lọ si ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Àkọlé fídíò, Ayo Ewebiyi Mama Oriki: Ọwọ́ Òbí, Ìjọba àti àwọn Ọba ni ìdágbàsókè Yorùbá wà lásìkò yìí

'' Gẹgẹ bi a se mọ, paapa julọ awọn to wa ni ile ẹjọ lonii nibi ti ile ẹjọ to n gbọ ẹjọ osisẹ ti pasẹ lori ẹjọ ti ijọba apapọ ati ẹgbẹ awọn dokita pe, idajọ naa ko tẹ wa lọrun "

" Lẹyin ti a fi ikuluku pẹlu agbẹjọro wa, ati ni ki o pe ẹjọ kotẹmilọrun ki o si pe fun ki idajọ naa duro titi wọn yoo fi pe ẹjọ".

Saaju ni oni yii ni ile ẹjọ ti ni ki awọn dokita ile iwosan ijọba pada si ẹnu iṣẹ ninu idajọ ti Adajọ Bashar Alkali ṣe pe ki wọn pada si ẹnu isẹ

FG vs resident doctors: Ẹ padà sí ẹnu iṣẹ́ yin ni kíá- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún àwọn dókítà

FG vs resident doctors: Ẹ padà sí ẹnu iṣẹ́ yin ni kíá- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ fún àwọn dókítà

Ile- ẹjọ to n gbọ awuye-wuye Lori iyanselodi laarin ijọba apapọ (Nigeria Industrial court) ati ẹgbẹ awọn dokita lorile ede Naijiria ti paa laṣẹ pe ki wọn pada sẹnu ise wọn ni kiakia.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

Ki wọn si bere ise wọn leye o-sọka

Bakan naa, ni ile -ejo tun paa lase pe ki egbe awon dokita ati ijoba lo fori-kori Lati yanju aawọ to wa laarin wọn ni itubi-inubi.

Bakan naa,ni ile -ẹjọ tun ni ki awọn agbejọrọ ijọba ati ẹgbẹ awọn dọkita lo forikori, ki wọn si mu ojo ti wọn yoo pada wa sile ẹjọ

Adajo Basha.A.Alkali lo dajo bẹẹ pe ki awon dokita pada senu ise won ni kiakia

Femi Aborisade to be agbẹjọro fun ẹgbẹ awọn dokita to gun le iyanselodi ti ni awọn yoo forikori pẹlu awọn onibara wọn, iyen ẹgẹe awọn dokita boya wọn yoo tesiwaju nibi ẹjọ to wa nile ẹjọ kotẹmilọrun, tabi ki wọn fopin si iyanselodi ohun

Chris Ngige ati Dokita Uyilawa Okhuaihesuyi

Oríṣun àwòrán, Chris Ngige

FG vs resident doctors: Òní nilé ẹjọ́ yóò dájọ́ lórí awuyewuye owó oṣù àwọn dókítà pẹ̀lú ìjọba

Oni ni ile ẹjọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ ati ileeṣẹ, NIC niluu Abuja yoo ṣe idajọ lori awuyewuye owo oṣu ati owo ajẹmọnu awọn dokita ati ijọba apapọ.

Àkọlé fídíò, Oloye Peter Fatomilola: Ọjọ̀gbọ́n olùkọ́ni ni Jesu àti Orunmila jẹ́, àwòkọ́ṣe sí rere si n

Adajọ Bashar A. Alkali sun igbẹjọ naa si ọjọ Ẹti oni lasiko igbẹjọ to waye ni Ọjọru.

Awọn dokita ti n yanṣẹlodi lati ọsẹ meloo kan bayii lati fẹhonu han lori owo ti wọn ni ijọba n jẹ awọn.

Agbẹjọro ẹgbẹ awọn dokita, Femi Falana (SAN) ti kọkọ sọ pe ile ẹjọ naa ko lagbara to lati gbọ ẹjọ naa.

Ṣugbọn aggbẹjọro ijọba apapọ, Tochukwu Maduka, ni ko si ọrọ ninu ohun ti Falana n sọ.

Àkọlé fídíò, Jẹ́ ká lọ sílu mi: Kò sí ìtàn Ibadan láìsí Efunsetan, Òkè méje, Bower's Tower àtàwọn ǹkan

Falana tun rọ ile ẹjọ pa ko paṣẹ wi pe ki ijọba ati ẹgbẹ awọn dokita pada lọ jiroro lori ati yanju ọrọ owo to da wahala silẹ.

Awon Dokita ti wa nile ẹjọ bayii niluu Abuja fun idajọ lori ọrọ naa.

Awon agbẹjọro to n ṣoju fun ẹgbẹ awon dokita ile iwosan ati aṣoju ẹgbẹ awọn dokita ile iwosan orile ede Naijiria si ti n fori kori.