Eunice Osayande: Wo ìlú tó fẹ́ sọ àdúgbò kan lórúkọ aṣẹ́wó pàtàkì tí wọ́n pa

Oríṣun àwòrán, Kevin Van den Panhuyzen/BRUZZ
Ilu Brussels ti ni àwọn yoo sọ ọkan lara adugbo ilu wọn lorukọ gbajumọ asẹwo ọmọ ilẹ Yoruba lati orilẹede Naijiria gẹgẹ bi ara ọna ti wọn yan lati polongo mimọ rírìi awọn obinrin lorileede wọn, Belgium.
Ilu naa ni adugbo naa yóò maa jẹ orukọ Eunice Osayande, ẹni ti onibara rẹ fi ibinu gun pa l'osu kẹfà ọdun 2018.
Eeyan kan lo seleri iṣẹ fún un tó si muu loju ni arabinrin Eunice fi lọ si olu iluu Belgium lọdun 2016.
Arabinrin Osayande lero pe osere ni awọn ọkunrin to pee pe kó máa bo tó si ro pe wọn yoo sọ oun di gbajumọ oṣere.
Biri, lọrọ ba yi pada, aṣe onifayawo láwọn araabi.
Kete to wọ ilu Brussels ni wọn fi tipatipa fa arabinrin Osayande wọ iṣẹ asẹwo. Wọn sọ fun un pe o n jẹ awọn onifayawo to muu wa ni iye owo to to €45,000 (£38,000; $52,000) to jẹ owo ọkọ, owo ile at'awọn nkan mii.

Oríṣun àwòrán, Kevin Van den Panhuyzen/BRUZZ
Nigba to ku ọsẹ diẹ ṣaaju iku rẹ, o ti kan sí asẹwo akẹgbẹ rẹ kan, Charity to si sọ fún wọn pé àwọn kan ni fi ọwọ ipa mu oun lẹnu iṣẹ. Ẹru baa lati lọ sọ fún olópàá tori arinrinajo ti ko niwe igbelu ni.
Ninu oṣu kẹfa nigba to pe ẹni ọdun mẹtalelogun ni wọn gùn Omidan Osayande lọbẹ nigba mẹtadinlogun eyi to wá lati ọwọ onibara rẹ fún ibalopọ ni ẹkùn Gare du Nord district.
Ìwọde kan wáyé èyí tí àwọn araalu ibi tí aṣẹ́wó yii n gbe ni Brussels. Awọn aṣewọde naa beere fun isẹ gidi wọn si n funpe si awọn aláṣẹ wọn ki wọn ṣe alakalẹ òfin ti yoo ti ẹ̀ka isẹ aṣẹ́wó lẹyin.
Isẹ aṣẹ́wó ko lodi si ofin ni Belgium àmọ́ ko fi bẹẹ si àgbájọwọ́ òfin nibẹ.
Maxime Maes to jẹ olùdarí ẹgbẹ́ awọn aṣẹ́wó ni Brussels lo sagbatẹru ìwọde náà.
"Iku Eunice ti da wa lagara ju paapaa torí àwọn araalu ibi tó ń gbé tí àwọn gan kò ní ìwé àṣẹ igbelu, o sọ fun BBC.
Wọn ti wa fi ẹ̀sùn kan ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan tó sì ń jẹjọ lọwọ. Bákan naa, ọwọ tẹ awọn mẹrin lara awọn onifayawọ ninu oṣù kini ọdun yii ti wọn si ti fi wọn si ẹ̀wọ̀n ọdun mẹrin.

Oríṣun àwòrán, Kevin Van den Panhuyzen/BRUZZ
Bi wọn si ṣe fẹ sọ adugbo kan lórúkọ tẹle Omidan Osayande, ilu Brussels ni àwọn fẹ fa ojú awọn eeyan si iranti "awọn obinrin to ti di igbagbe ti wọn si jìyà fayawọ, ifipabanilopọ ati ifiya jẹ obinrin ".
Adugbo ọhun ni yoo jẹ àkọ́kọ́ lorile-ede naa ti wọn sọ lórúkọ aṣẹ́wó lati maa ṣe ìrántí rẹ gẹgẹ bi ile isẹ iroyin Belgium kan, RTBF ṣe sọọ.
Adugbo tuntun ti yoo wà ní apá Àríwá Scharbeek jẹ ọkan lára ìgbésẹ àjọ naa lati sọ awọn adugbo mii lórúkọ ni iranti awọn obinrin.
Àjọ naa ti sọ awọn adugbo ni iranti awọn gbajumọ obinrin bíi Ajafetọ Yvonne Nèvejean and Andre De Jongh, ti wọn si sọ afara kan lórúkọ Suzan Daniel, ó ibalopọ abosabo ọmọ orílẹ̀èdè Belgium kan.
Omidan Poplier ni ida mejilelogoji obìnrin ni Belgium to wa laarin ẹni ọdun merindinlogun si mọkandinlaadọrin lo ti la ifipamuni kọja.
Ida yii wọpọ ju laarin awọn aṣẹ́wó. Eyi si ni idi ti Eunice Osayande ṣe di orúkọ adugbo.
Adugbo naa ti wọn ṣi n kọ lọwọ yoo di ṣíṣí ni oṣu to n bọ ti àjọ náà si ni wọn yoo pe awọn aṣẹ́wó wa to fi mọ adugbo táwọn arinrinajo wọlu ń gbe láti wá sọ̀rọ̀ nibi ifilọlẹ adugbo ọhun.
















