Sunday Igboho trial: Ìjọba àpapọ̀ yarí pé kò sí N20bn kankan fún Igboho, ó yá nílé ẹjọ́

Malami ati Igboho

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Ọrọ ti di isọrọ n gbesi laarin ijọba apapọ ati ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọ Yoruba, Ilana Ọmọ Oodua to ti n ja fun idalare ajafẹtọ Yoruba, Sunday Igboho fun igba diẹ bayii.

Ni ti Ilana Ọmọ Oodua, wọn ti fi ọrọ sita lati ṣapejuwe idajọ ti ile ẹjọ da fun nipa ikọlu ti ajọ DSS ṣe si ile Sunday Igboho n'Ibadan ati gbogbo nkan to bajẹ to fi mọ ẹmi awọn eeyan to ba iṣẹlẹ naa rin pe ẹjọ naa ṣafihan pe imọlẹ ti tan si ọrọ to wa nilẹ o si ti fi otitọ han.

Ẹjọ to jẹ jade ni ile ẹjọ giga ipinlẹ Oyo eyi ti adajọ Ladiran Akintola dari ni pe ki ijọba san biliọnu lọna ogun naira owo gba mabinu fun ọṣẹ ti ajọ DSS ṣe si ile Igboho ni ọjọ kini oṣu keje ọdun 2021.

Amọ lọjọ yii kan naa ni ijọba apapọ ti fi atẹjade tiwọn da esi pada pe ko tan sibi idajọ ti ile ẹjọ giga ilu Ibadan da rara o, ile ẹjọ kotẹmilọrun lo kan.

Agbẹjọro agba fun ijọba, Abubakar Malami lo kede ipinu ijọba apapọ lati pe ẹjọ kotẹmilọrun nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ ni Abuja.

Malami ni akitiyan ti n lọ lọwọ fun igbesẹ pipe ẹjọ kotẹmilọrun naa.

Ni ti Ẹgbẹ Ilana Omo Oodua eyi ti Ọjọgbọn Banji Akintoye n dari, wọn dupẹ fun ọna ti ile ẹjọ gba da ẹjọ naa wọn si ni ṣe ni ki ijọba bọwọ fun ofin ki wọn si san N20bn naa lai fi akoko ṣofo rara.

Ni idahun si gbogbo ẹri ti agbẹjọro Sunday Igboho, Yomi Aliyu mu wa, Malami ni ko si aridaju kankan niwaju ile ẹjọ pe ẹjẹ ti wọn ri ninu fidio ti wọn wo jọ ẹjẹ ọmọ eniyan atipe ile ti wọn fihan ninu fidio ọhun gan ko si aridaju pe ti Igboho ni.

O wa fọhun pe ki ile ẹjọ wọ ẹri ati gbogbo ipẹjọ wọn danu.

Agbẹjọro ajọ DSS, Ọgbẹni T.A Nurudeen ni aridaju gbudọ wa latọdọ dokita onimọ nipa ẹjẹ lati ṣafihan pe lootọ ẹjẹ eeyan ni wọn ri ninu fidio naa.

Bakan naa, Nurudeen naa ṣafihan fidio kan fun ile ẹjọ nibi ti wọn fẹsun kan Sunday Igboho pe o n dẹru bolẹ lati da Oduduwa Republic silẹ to si n rọ awọn Yoruba lati di ara lamure pẹlu oogun ati ibọn.

Ẹwẹ, lasiko to n ka idajọ rẹ, adajọ Ladiran Akintola ni ilana ti ajọ DSS lo lati lọ si ile Sunday Igboho lasiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹ ko ki n ṣe ti ẹni to mọ iṣẹ.

Iléẹjọ́ ti ní kí ìjọba Nàìjíríà san ogún bílíọ̀nù fún Sunday Igboho gẹ́gẹ́ bí owó gbà má bínú!

Pẹlu ariwo ayọ ni awọn ololufẹ Oloye Sunday Igboho fi idunnu han ni isinyii ni ile ẹjọ ni Ibadan.

Adajo ile ẹjọ giga ni ilu Ibadan nibi ti Sunday Igboho ti pe ẹjọ yii tako ajọ DSS ati ijọba apapọ lo ti waye.

Ogun bilionu naira ni Adajo Ladiran Akintola ti ni ki ijoba san fun Sunday Igboho gege bii owo gba ma binu

Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Others

Lónìí ni ìdájọ́ yóò wáyé lórí N5.5b tí Sunday Igboho bèèré lẹ́yìn ìkọlù DSS sílé rẹ̀

Idajọ lori ẹjọ oni N500bilionu fun ile re ati awon ohun ini re ti won baje ati 500 milionu fun awon nkan ara re ti Oloye Sunday Adẹyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si "Sunday Igboho".

O pe ẹjọ naa tako ijọba apapọ nipasẹ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS yoo waye lonii nile ẹjọ giga to n bẹ nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Ọyọ.

Agbẹjọro fun Sunday Igboho, Yọmi Aliyu lo ti n le iwaju igbẹjọ naa lẹyin ikọlu ti ajọ DSS ṣe si ile ajafẹtọmọniyan naa to n bẹ ni agbegbe Soka ilu Ibadan.

Ọjọ kinni, oṣu kẹje, ọdun 2021 yii ni iṣẹlẹ ọhun waye nibi ti ọpọlọpọ dukia ati ẹmi eeyan meji ti ṣofo.

Ọkanojọkan iwadii lo ti waye saaju asiko yii lati igba ti igbẹjọ naa bẹrẹ, ṣugbọn lonii ni igbẹjọ naa yoo yọri.

Gbogbo bo ba se n lọ nibẹ lonii ni BBC Yoruba yoo maa muwa si oju opo yin.