VAT: Àwọn gómìnà Gúùsù sọ àbábọ̀ ìpàdé wọn lóríi VAT, ààrẹ fún ọ́dún 2023

Awọn gomina ìhà Guusu orilẹede Naijiria ti ṣafihan atilẹyin wọn fún gbigba owo lori ọja (Value Added Tax - VAT) eyi ti awọn ijọba ibilẹ kan n gba.
Gomina Rotimi Akeredolu to jẹ ọkan lára àwọn to ṣepade lo sọ eyi lasiko to n ka iwe afenuko awọn gomina nigba ti wọn pari ìpàdé náà ni Ọjọbọ niluu Enugu, ipinlẹ Enugu.
Akeredolu to je gomina ìpínlẹ̀ Ondo ni awọn gomina Pohun pọ awọn fi ọwọ síi lati satileyin fún ki ipo gbigba owo ori ọja bọ sí ọwọ ìjọba ìpínlẹ̀.
Ìpàdé náà tún fi ifarajin wọn hàn sí àwọn nkan to yẹ ki ijoba àpapọ maa ṣe ti wọn sì tẹnu mọ ko farahan. ninu ofin Naijiria pẹlu ilana àtúnṣe tí wọn n ṣe lọwọ.
- Ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí mi láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Femi Fani-Kayode
- A ti gbálé ati gbáta, kò sí ǹkankan lọ́wọ́ wa mọ́ ni a ṣe kígbe síta- Adebisi Aisha, Ọmọ Iyabo Oko
- Nkechi Blessing ò lè fẹ̀sùn ibálòpọ̀ láti gba "role" kàn mí láyé! Tó bá dán an wo... - Damola Olatunji
- Àwọn jàndùkú jí Emir Bungudu gbé, wọ́n pa ọlọ́pàá lọ́nà mọ́rosẹ̀ Abuja sí Kaduna
- Àwa ọmọ Iyabo Oko ló dá owó gọbọi fi gbé ìyá wa lọ sí India fún ìtọjú- Ewa, ọmọ Iyabo Oko
- A mọ̀ bó ṣe ń jáa yín lára jẹ tó, a ó dá Twitter padà láipẹ́ - Ìjọba àpapọ̀
- Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn kankan ní orúkọ mi- Sunday Igboho
Akeredolu wa rọ àwọn ìpínlẹ̀ to wa ni Guusu ki wọn lọ anfani agbara ile asofin ìpínlẹ̀ wọn at'awọn aṣoju wọn nile asofin agba lati ri amuṣe eyi.
Ọrọ bibẹgi dina dida ẹran maalu jẹko láwọn ipinlẹ to wa nílẹ̀ Yorùbá ko gbẹyin gẹgẹ bí wọn ṣe fi idunnu wọn hàn síi pé o wa ni ibamu pẹlu alakalẹ èròngbà awọn gomina Guusu tẹlẹ ti wọn sì rọ àwọn tí kò tii fi le'lẹ nipinle wọn lati ṣe bẹẹ kiakia.
Lara ohun to tun jẹyọ níbẹ ni nipa idibo ti yóò wáyé lọdun 2023 eyi ti wọn tun tẹpẹlẹ mọọ pe ẹkun Guusu Naijiria ni ààrẹ to kan yóò ti wa.










