Iyabo Oko Illness: Ọmọ Iyabo Oko ní kò sí ńkankan mọ́, ló jẹ́ kí ẹbí bẹ̀bẹ̀ ìrànwọ́ lórí àìlera màmá òun

Iyabo Oko ati Omo rẹ

Oríṣun àwòrán, Foluke Daramola

Ọmọ Odunkanmi Kudirat ti gbogbo eniyan mọ si Iyabo Oko ti ke gbajare si gbogbo awọn ọmọ Naijiria, awọn ẹgbẹ osere TAMPAN ati awón ololufẹ iya rẹ lati dide adura ki ẹmi iya maa bọ.

O sọ eyi lasiko to n se ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba nitori iya rẹ to dubulẹ Aisan ni ile iwosan kan ni ilu Oyo.

Adebisi Aisha to jẹ ọmọ Iyabo Oko ṣalaye gbogbo nkan ti awọn ọmọ ti se lati toju iya wọn lati bi ọdun marun ṣẹyin lori itọju iya wọn.

Aisha ṣalaye pe ẹbẹ kan ti oun bẹ awọn eniyan ni lati wolẹ adura ati ṣiṣe iranwo owo fun iya oun ki o le dide lori akete aisan to wa.

Ninu ọrọ rẹ, o ni lati igba ti iya awọn ti ṣe aisan ni awọn ti gbale gbata lati lo se itọju rẹ loke okun ati pe ati asiko yii ni awọn ọmọ Iyabo oko to ti bọ sipo mọ.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

O ni lootọ ebi o pa awọn sùgbọn awọn ko yọ, sibẹ apa awọn ẹbi ko ka owo ti ile iwosan n bere fun itọju iya wọ.

Bakan naa lo sọ pe itọju ko duro lati bi ọdun marun sẹyin, gbogbo igba ni awọn si n nawo fun ilera mama.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Ọmọ gbajumọ oṣere naa to ni ẹni ọdun mẹrindinlaadọrin ni mama fi kun un pe oun dupẹ lọwọ gbogbo awọn to ti dide iranwọ sugbọn sibẹ awọ ko tii ka oju ilu iye owo ti awọn nilo fun itọju.

Lasiko ifọrọwerọ naa, ni gbajugbaja osere tiata to maa n gbe ọrọ awọn arugbo inu ẹgbẹ jade Foluke Daramola- Salako pẹlu ṣalaye awọn nkan ti awọn ọmọ ẹgbẹ ti ṣe ati ipa ribiribi ti oun pẹlu n ko lori ọrọ Iyabo Oko.

Foluke Daramola ṣalaye pe ẹgbẹ n gbiyanju ipa ti wọn le sa lati ri daju pe awọn ọmọ ẹgbẹ gbe igbe aye to dara, sugbọn o ṣeni laanu pe, awọn igbese tuntun yii ṣẹṣẹ n bẹrẹ ni ti ko si kan awọn to ti dagba ninu ẹgbẹ.

Gbajugbaja Osere fi kun un pe ọmọ mama gan an lo pe oun pe ara mama ko ya o si lagbara gidi, nitori naa awọn nilo iranwọ fun wọn.

Àkọlé fídíò, Ijesha tennager police death: O yẹ kí wọ́n máa yẹ ọpọlọ ọlapàá wò kí wọ́n tó gbà wọn síṣẹ

O ṣalaye pe ilẹ to mọ loni, awọn ti rí owo to ti fẹẹ to miliọnu meji naira, sugbọn iye ti wọn nilo gan ju miliọnu marun Naira lọ.

Bakan naa lo dupe pupọ lọwọ awọn Naijiria fun awọn nkan ti wọn se nitori pe ẹlomiran tilẹ fi ọgọ naira ransẹ, eyi si fi han pe awọn eniyan nifẹ mama naa.

Àkọlé fídíò, Oloye Peter Fatomilola: Ọjọ̀gbọ́n olùkọ́ni ni Jesu àti Orunmila jẹ́, àwòkọ́ṣe sí rere si n