Eèmọ̀ wọ̀lú, ẹni tó ń ta ọtí àti ògógóró gún Oníbárà rẹ̀ pa ní Osun!

Oríṣun àwòrán, others
Arakunrin kan to n ta ogogoro ni agbegbe Ifon Orolu nipinlẹ Osun ti ko si gbaga ọlọpaa lẹyin to gun ọkan lara awọn onibara rẹ pa lasiko ti wọn n ja.
Afurasi to n ta ogogoro naa, Mumimi Olanipekun ni o gun Wale onibara rẹ pa, to si gbe ara rẹ lọ si agọ ọlọpaa lẹyin iṣẹlẹ naa.
Iroyin gbe e pe ija bẹ silẹ laaarin Olanipekun ati Wale to wa mu ogogoro ni ṣọọbu Olanipekun.
Lasiko ija naa ni Olanipekun fi afọku igo gun Wale ni ọrun ati ikun rẹ, ko to di pe Wale gbe ẹmi mi loju ọna ti wọn ti n gbe lọ si ileewosan.
''Ọjọ isinmi ni iṣẹlẹ naa waye, Mumini Onanipekun wọ iya ija pẹlu Wale to jẹ onibara rẹ igba gbogbo. Lasiko ija naa ni Olanipekun gun Wale pẹlu afoku igo ni ikun ati ọrun rẹ.''
''Wale ko ku lẹsẹkẹsẹ, amọ asiko ti wọn n gbe digbadigba lọ si ileewosan lo gbẹmi mi.''
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni wọn ko le e sọ pato ohun to fa ija laarin awọn mejeeji, amọ jinijini bo awọn ara agbegbe naa lẹyin iṣẹlẹ ọhun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun, Yemisi Opalola fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ, to si fikun pe iwadii nlọ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa.
- Femi Ojudu faṣọ iyí mọ́ Kayode Fayemi lára, Ó ní ojú ń gba òun ti fún ipò táwọn títì Ekiti wà
- Wo bí ọlọ́jọ́ ṣe dé fún Ola Ibironke, olówó orí Bimbo Oshin àti ibi tó parí iṣẹ́ sí
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
- Òní lòní ń jẹ́, ìwọ́de ènìyàn mílíọ̀nù kan yóò wáyé ni New York lórí òmìnira ìran Yorùbá
- Bí ọwọ́ wa kò bá tẹ àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kabba, a kò ní sinmi- Aregbesola














