Covid-19 cure: ìjọba àpapọ̀ ké pe àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ láti wá oògùn Coronavirus

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad
Ijọba apapọ ti kepe awọn oniṣegun ibilẹ lati ṣe awari oogun ajakalẹ arun coronavirus to n ṣọṣẹ lorilẹede Naijiria.
Minisita abẹle fun eto ilera ni Naijiria, Dokita Olorunnimbe Mamora lo sọrọ yii nibi ayẹyẹ ayajọ oogun ibilẹ to waye niluu Abuja.
Minisita ni ọrọ ajakalẹ arun coronavirus ti de ibi ti awọn oniṣegun ibilẹ ni lati da si ọrọ ati wa oogun si arun naa lọna ti ibilẹ.
- Lóòtọ́ ni ìyá yìí bímọ méjì fún ọmọ rẹ̀ tó ń bá sùn, ohun tí a ṣe síi rèé - Àjọ NSCDC Kwara
- Àwọn jàndùkú jí Emir Bungudu gbé, wan pa ọlọ́pàá lọ́nà mọ́rosẹ̀ Abuja sí Kaduna
- 'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́yẹn o àmọ́...'
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
- Atọ́kùn egúngún, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn méjì àtìmọ́lè lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn ní mọ́ṣálááṣí
- Eèmọ̀ wọ̀lú, ẹni tó ń ta ọtí àti ògógóró gún Oníbárà rẹ̀ pa ní Osun!
- Ìwọ́de Yoruba Nation lólú iléeṣẹ́ àjọ UN wáyé, bó ṣe lọ nìyí
Dokita Mamora ṣalaye pe ijọba ti sọ fun ajọ NIPRD to n ri si pipoogun ati NAFDAC lati wa oogun covid-19 lati Naijiria.
Ọrọ yii jade lẹyin ti adari ajọ alaanu Bill & Melinda Gates Foundation (BMGF), Dokita Mark Suzman, ṣe bu ẹnu atẹ lu aidọgba to wa ninu pinpin abẹrẹ ajẹsara laarin awọn orilẹede to lowo atawọn ti ko rọwọ họri.
Dokita Suzman ni iru nkan bayii ko boju mu, ati pe o le ṣakoba fun ọrọ aje fun igba pipẹ.
O ṣalaye pe bi ida ọgọrin ninu abẹrẹ ninu abẹrẹ ajẹsara covid-19 ti wọn n pin lagbaaye bayii lo n lọ si awọn orilẹede to lowo nigba ti ida kan ṣoṣo n lọ sawọn orilẹede ti ko rọwọ họri.
Dokita Suzman pe fun imugbooro pinpin abẹrẹ ajẹsara papaa julọ nilẹ Afirika nibi ti wọn ti n ri abẹrẹ perete gba.
Suzman ni ajọ alaanu BMGF atawọn ijọba orilẹ-ede agbaye kan lo da COVAX bi ọdun kan sẹyin lati fi le pin abẹrẹ covid-19 kaakiri gbogbo orilẹede agbaye.
- Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa òògùn ìbílẹ̀ Coronavirus tí Ooni filọ́lẹ̀? Ó ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tó ní Covid-19 ló ti gbádùn
- Gba abẹ́rẹ́ Covid-19 kí o fi ọtí, "Doughnut", ẹ̀bùn owó ọ̀fẹ́ ṣararindin
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
Amọ, o ni ọrọ ko ri bẹ mọ lẹyin tawọn orilẹ-ede to lowo n ko abẹrẹ naa pamọ ti wọn ko si jẹ ko kari.
Dokita Suzman sọ pe o yẹ ki ajọ iṣọkan agbaye jiroro ninu ipade wọn lori bi wọn ṣe maa gbe owo kalẹ lati fi ṣe iranwọ fun pinpin abẹrẹ covid-19 kari aye.















