Kaduna kidnap: Àwọn jàndùkú jí Emir Bungudu gbé, wọ́n pa ọlọ́pàá lọ́nà mọ́rosẹ̀ Abuja sí Kaduna

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abdulrahman Hussaini
Eto abo to mẹhẹ ni Naijria papaa julọ lẹkun ariwa ti wa n buruu si bayii.
Lọjọ Iṣẹgun ni iroyin kan jade pe awọn janduku ajinigbe pawo gbe Emir Bungudu, Alhaji Hassan Attahiru lọ lopona ilu Abuja si Kaduna.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, Mohammed Jalige lo fid iṣẹlẹ ọhun mulẹ ninu atẹjade to fi sita lalẹ ọjọ Iṣẹgun.
- Atọ́kùn egúngún, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn méjì àtìmọ́lè lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn ní mọ́ṣálááṣí
- 'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́yẹn o àmọ́...'
- Ìwọ́de Yoruba Nation lólú iléeṣẹ́ àjọ UN wáyé, bó ṣe lọ nìyí
- Lóòtọ́ ni ìyá yìí bímọ méjì fún ọmọ rẹ̀ tó ń bá sùn, ohun tí a ṣe síi rèé - Àjọ NSCDC Kwara
- Ọ̀gá ọlọ́pàá Èkó kàn sí ẹbí Monsurat tí ọlọ́pàá yìnbon lù
- Wo ọmọ Nàìjíríà mẹ́fà tí UAE ń wá lórí ẹ̀sùn ṣíṣe àtìlẹ́yìn owó fún Boko Haram
- Wo bí Pásítọ̀ Adeboye, Wòlíì Iginla ṣe ń dárò ikú akẹgbẹ́ wọn David Yonggi Cho
Jalige ṣalaye ninu atẹjade naa pe ọlọpaa kan dero ọrun lasiko ikọlu naa to ṣẹlẹ lagbegbe ilu Dutse lopona Abuja si Kaduna.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ọpọ eeyan ni wọn jigbe lọ pẹlu Emir Bungudu nigba ti awọn meji mi farapa yana yana.
O ni awọn ti wọn farapa naa ti n gba itọju bayii nile iwosan.
Jalige fikun ọrọ rẹ pe ṣadeedee lawọn ajinigbe ọhun da awọn ero ọkọ naa lọna ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn ni mẹsan an mẹwaa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ẹṣọ eleto abo gbera pa lọ sibẹ lati doola awọn eeyan, ṣugbọn ọlọpaa kan ba iṣẹlẹ naa lọ.
O ni ọkọ mẹrin ni ileeṣẹ ọlọpaa ri nibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye nigba ti o sọ pe oun ko le sọ pato iye eeyan ti wọn jigbe lọ.
''Emir Bungudu wa lara awọn ti wọn jigbe lọ si ibi ti ẹnikan ko mọ bayii.
Ṣugbọn iṣẹ n lọ lọwọ lati doola gbogbo awọn ti wọn jigbe lọ lai ni ifarapa.
Iru iṣẹlẹ ijinigbe yii ko saaba wọ pọ mọ lopopona Abuja si Kaduna lẹnu ọjọ mẹta yii ki eleyii to ṣẹlẹ,'' Jalige lo sọ bẹẹ.
Ẹwẹ, ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, CP Mudassiru Abdullahi ti rọ awọn eeyan pe ki wọn maa ṣe bẹru lati maa rinrin ajo lopopona Abuja si Kaduna.
CP Abdullahi ni awọn ọlọpaa ko ni kaarẹ lati maa pese abo to peye fawọn eeyan loju ọna ọhun.
- Báyìí ni ìrìnàjò àìsàn Iyabo Oko ṣe bẹ̀rẹ̀ láti ọdún márùn ún ṣẹ́yìn
- 'Ó lé ni akẹ́kọ̀ọ́ 1,000 tí àwọn ajínigbé kó láàrin oṣù kíni sí ìkẹjọ 2021'
- Ìjọba àpapọ̀ sọ̀rọ̀ lórí bí ọmọ ilẹ̀ Italy ṣe pa ìyàwó rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Naijiria
- Bí ọwọ́ wa kò bá tẹ àwọn tó lọ́wọ́ nínú ìkọlù sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Kabba, a kò ní sinmi- Aregbesola
- Kókó nǹkan tí ẹgbẹ́ NINAS ń bèrè fún ní ibi ìpàdé UN General Assembly
- Wo iye àwọn tó ti gbẹ̀mí ara wọn ní Nàìjíríà láàrin ọdún mẹ́rin ìjọba Buhari
















