Mother gives birth for son: Àjọ NSCDC Kwara ṣàlàyé kàyééfì tó mú ọmọ má a ba ìyá rẹ̀ lòpọ̀

Ọmọ ati iya rẹ to n ba lopọ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Eemọ ati kayefi parapọ̀, wọn bẹ silẹ ni ilu Kaiama ni ipinlẹ Kwara nibi ti iroyin ti jade pe arakunrin kan n ba iya rẹ lajọsepọ ti ọmọ mẹta si ti tara Ibalopọ wọn jade.

BBC Yoruba gbọ pé àwọn to n se eyi kii ṣe Yoruba torinaa la ṣe kan sí àjọ abo ara ẹni labo ilu (NSCDC) ti atẹjade kan ti ọwọ wọn wa.

Ajọ NSCDC ipinlẹ Kwara sọ fun BBC Yoruba pe ọwọ awọn tẹ afurasi ọkunrin naa, Adamu Sabi Sime to jẹ ọmọ orilẹede Benin Republic to n ba iya rẹ to bii lọmọ lajọṣepọ ọhun.

Ninu atẹjade ti wọn fi sita, alukoro ajọ NSCDC, Babawale Afolabi ni lọjọ Satide ni awọn ri aridaju pe lootọ arabinrin naa, Fati Sime ti bi ọmọ mẹta fun ọmọ rẹ gangan.

"Awọn oṣiṣẹ ẹka amulo ọgbọn ni ajọ naa ẹka ti ilu Kaiama kan lu agbami iṣẹ ababọ iwadii wọn si ni wipe aridaju wa pe iya ọhun Fati ni ọmọ mẹta fun ọmọkunrin to bi ninu ara rẹ.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Ẹwẹ, Babawale jẹ ko di mimọ fun BBC Yoruba pe o da bi ẹni wipe iya naa ni idamu inu ọpọlọ, eyi si lo mu ki awọn ọmọ rẹ ọkunrin maa jẹ anfani lara rẹ nipa bibaa lajọṣepọ to si n di oyun to tun n di ọmọ.

Amọ o ni awọn ti fi wọn ranṣẹ si orilẹede ti wọn ti wa pada iyẹn Cotonou ti ko jina rara si orilẹede Naijiria.

Àkọlé fídíò, Adene Oluwabukola Deborah: Bàbá mi kò kọ́kọ́ fọwọ́ sí iṣẹ́ ìlù lílù ṣùgbọ́n....

Iwadii fihan pe eyi aburo ọkunrin naa n ba iya wọn lajọṣepọ bakan naa amọ oun ti na papa bora ni tirẹ.

Ajọ NSCDC ni aainrin ọhun atawọn ọmọ rẹ ko ni awọn iwe ẹri to yẹ lati gbe lorilẹ-ede Naijiria o si fi kun un pe awọn ti ko wọn le ajọ to n risi iwọlewọde ajoji lọwọ ti wọn si gbe igbesẹ to yẹ.