Warplane caught fire in Yobe:: Báàlù ológun tó já, to ṣekú pa àwọn ará ìlú Buhari ṣẹlẹ̀ nítòòtọ́- Nigerian Air Force

Oríṣun àwòrán, @Others
Ni irọlẹ ana, ọjọru, ọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹsan an, ọdun 2021 yii ni baalu iajgun kan ja ni agbegbe Buhari ni ipinlẹ Yobe.
Oriṣiriṣi ariwisi ni awọn eniyan Naijiria ti n sọ nipasẹ iṣẹlẹ naa yatọ si pe ileeṣẹ ologun kọkọ sẹ pe ko ṣẹlẹ ki wọn to wa sọ pe o tun ṣẹlẹ laarọ oni.
Eyi lo mu ki a ṣe akojọpọ iye igba ti baalu ologun ti ja ni Naijiria laipẹ yii.
- Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn kankan ní orúkọ mi- Sunday Igboho
- Ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí mi láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Femi Fani-Kayode
- ''Ìjọba, ẹ má da àwa tó ń ṣagbátẹrù Yorùbá Nation pọ mọ IPOB''
- ''APC yóò fún Goodluck Jonathan ní ànfàní láti dupò ààrẹ lọ́dún 2023 tó bá darapọ̀ mọ́ wa''
- Mi ò sọ pé àwọn tó ń pè fún Yorùbá Nation kò yàtọ̀ sí Boko Haram o- Gbajabiamila ṣàlàyé
- Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run
- A mọ̀ bó ṣe ń jáa yín lára jẹ tó, a ó dá Twitter padà láipẹ́ - Ìjọba àpapọ̀
- Ẹ máa gbàá nìṣò, àwa Gómìnà ìhà Gúúsù f'ọwọ́ sí kí ìpínlẹ̀ má gba VAT
Lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kinni, ọdun 2017 ni ọkan waye pẹlu ikọ ologun ofurufu ni Naijiria ni Maidugurito jẹ olu ilu ipinlẹ Maiduguri ni ariwa Naijiria nibi ti eeyan mejilelaadọta ti gbẹmi mi.
Lara awọn to ku ni awọn oṣiṣẹ eleto ilera, oṣiṣẹ iranẹnilọwọ ati awọn ajọ apese iranlọwọ ni ariw.
Iṣẹlẹ yii bi Ige ati Adubi lọdọ awọn ọmọ Naijiria eyi ti ikọ ologun ofurufu pada sọ pe aṣiṣẹ ni o fa a.
Lọdun 2019 ni awọn eeyan mọkandinlogun mii tun jalaisi ni abule Gajigana ni ipinlẹ borno.
Eyi waye leyin ti awọn ologun ofurufu Naijiria ni awọn n kọlu awọn Boko Haram alakatakiti.
Laipe yii ni ilu Port harcourt ni ipinlẹ rivers ni guusu Naijiria ni baalu to n ju ado oloro tun kolu bootu onigi to n ko ohun jije ati ero ni osu kẹjọ odun.
Ileeṣẹ aabo Naijiria fi atẹjade sita pe wọn ko mọ nipa bootu naa tabi nipa awọn ero ati ohun jijẹ ti wọn n ko ati pe awọn to n ji epo rọbi wa ni awọn sọ ọ si.

Oríṣun àwòrán, @Nig Airforce
A kò mọ̀ọ́mọ̀, bàálù ìjagun tó pa àwọn eèyàn Yobe náà ṣèèṣì jábọ́ ni- Iléeṣẹ́ Ológun Nàìjíríà
Ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu ti fi ikede sita pe nitootọ ni baalu ijagun kan ja ni ilu Buhari ni ipinlẹ Yobe.
Saaju ni awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ti kọkọ sọ pe eeyan mẹ́wàá lo ba iṣẹlẹ naa rin.
Ni kete ti iṣẹlẹ yioi ṣẹlẹ ni ana ni ileeṣẹ ologun Naijiria ti sọ pe irọ ni.
Wọn ni ko si ohun to jọ beẹ.
- Yorùbá Nation, yàgò fún IPOB níbi ìwọ́de tó ń lọ lọ́wọ́ ní New York bí bẹ́ẹ̀kọ́....- Ìjọba Buhari
- ''APC yóò fún Goodluck Jonathan ní ànfàní láti dupò ààrẹ lọ́dún 2023 tó bá darapọ̀ mọ́ wa''
- Mi ò sọ pé àwọn tó ń pè fún Yorùbá Nation kò yàtọ̀ sí Boko Haram o- Gbajabiamila ṣàlàyé
- Ọkùnrin tó lẹ ''Super Glue'' mọ́ ǹkan ọkùnrin rẹ̀ láti rọ́pò ''condom'' ti dèrò ọ̀run
- Wo ọ̀nà méje tí o lè fi dáàbò bò ọmọ rẹ níbàyìí tí iléẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ padà
Sugbon bayii, ileeṣẹ ologun ofurufu ni Naijiria ti kede pe lootọ lo ṣẹlẹ.
Wọn ti fi atejade sita pe asise ni iṣẹlẹ naa to fa ijamba to mu ẹnmi awọn eniyan kan lọ.
Ogagun Edward Gabkwet to jẹ adari agba ni NAF lo buwọlu atẹjade naa.
Bawo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀?
Ogagun Edward ni pe won fi baalu ijagun naa lọ si agbegbe Kamadougou Yobe ni lati fi koju awon onise ibi Boko Haram ati ISWAP ko to ja.
O ni Operation Unity to jẹ iṣẹ akanṣe nibẹ gba ifitonileti pe awọn oniṣẹ ibi kan ti fẹ ṣọṣẹ ni agbegbe naa ni.

Oríṣun àwòrán, Twitter
Báàlù ìjagun kan já lulẹ̀ ní ìlú Buhari, ẹ̀mi àwọn aráàlú bọ́
Báàlù ìjagun kan ti gbiná nílùú Buhari, ẹ̀mi àwọn aráàlú bọ́
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo lati ipinlẹ Yobe ni pe baalu ijagun kan ti ẹnikẹni kò mọ ti gbina ni abule kan to n jẹ Buhari ijọba ibilẹ Yunusari l'owurọ Ọjọbọ tó si ti pa ọpọlọpọ araalu.
Awon olugbe ilu naa sọ fún BBC awọn ti kọkọ rí baalu ijagun mẹta to n fo l'oke.
Nigba to ya, ọkan ninu wọn dede gbina lapa ibomii ninu ilu naa to sì pa eeyan oun kan ati ìdílé rẹ, araalu kan sọ fún BBC.
"O ṣẹlẹ pé ni nkan bíi ago mẹjọ abọ owurọ ti ọkan lára àwọn baalu na lulẹ nibi kan ninu ilu to si gbina, gbogbo ile to wà lápá ibẹ lo jona to bajẹ.
O jẹ ọkọ baalu ijagun nla ti awon ologun ṣugbọn a o mọ pato ibi to ti wa," o sọ fún wa.
Osojumikoro to wa níbẹ ni awọn o le sọ iye èèyàn to ti ba iṣẹlẹ naa lọ bayii, "torí pé ninu ile wa nikan, a ti padanu eeyan meji bayii," araalu yii sọ fún BBC.
- Àwa ọmọ Iyabo Oko ló dá owó gọbọi fi gbé ìyá wa lọ sí India fún ìtọjú- Ewa, ọmọ Iyabo Oko
- Èmi tí wọ́n kọ́kọ́ pé ọkọ Bimbo kú gàn an ti di jálajála lórí ìròyìn burúkú náà- Jaye Kuti, ọ̀rẹ́ Bimbo Oshin
- Ẹ̀yin oníṣègùn ìbílẹ̀, ẹ bá wa ṣe àwárí oògùn àjákálẹ̀ àrùn covid-19- Ìjọba Naijiria
- Ìwọ́de Yoruba Nation lólú iléeṣẹ́ àjọ UN wáyé, bó ṣe lọ nìyí
- Lóòtọ́ ni ìyá yìí bímọ méjì fún ọmọ rẹ̀ tó ń bá sùn, ohun tí a ṣe síi rèé - Àjọ NSCDC Kwara

















