Yoruba Nation: Femi Gbajabiamila ní àwọn èèyàn kan ló si òun gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ tóun sọ nípa Yorùbá Nation

Oríṣun àwòrán, Femi Gbabiamila
Adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin niluu Abuja, Femi Gbajabiamila ti ṣalaye pe oun ko sọ pe awọn to n pe fun idasilẹ Yoruba Nation ko yatọ si ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram.
Ni Ọjọru ni iroyin gbee Gbajabiamila sọ pe ẹgbẹ IPOB to n pe fun idasilẹ orilẹede Biafra ati Yoruba Nation ko yatọ si Boko Haram.
Amọ, oludamọran adari ile igbimọ aṣoju-ṣofin lori ọrọ iroyin, Lanre Lasisi sọ ninu atẹjade to fi sita pe ọrọ ko ri bẹẹ.
- Lóòtọ́ ni ìyá yìí bímọ méjì fún ọmọ rẹ̀ tó ń bá sùn, ohun tí a ṣe síi rèé - Àjọ NSCDC Kwara
- Báàlù ìjagun kan já lulẹ̀ ní ìlú Buhari, ẹ̀mi àwọn aráàlú bọ́
- 'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́yẹn o àmọ́...'
- Sunday Igboho ránṣẹ́ tuntun nípa agbẹjọ́rò rẹ̀ ní Benin republic, Ó ní...
- Atọ́kùn egúngún, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn méjì àtìmọ́lè lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn ní mọ́ṣálááṣí
- Eèmọ̀ wọ̀lú, ẹni tó ń ta ọtí àti ògógóró gún Oníbárà rẹ̀ pa ní Osun!
- Ìwọ́de Yoruba Nation lólú iléeṣẹ́ àjọ UN wáyé, bó ṣe lọ nìyí
Ọgbẹni Lasisi ṣalaye pe Gbajabiamila ko darukọ ẹgbẹ ajijagbara kankan ninu ọrọ rẹ.
''Oun ti adari ile igbọmi aṣoju-ṣofin sọ pe awọn ọdaran kan n lo iwọde tawọn kan fi n pe fun iyapa kuro lara Naijiria lati da rogbodiyan silẹ.
Ọpọ awọn ọdaran to n pe ara wọn ni ajijagbara lapa Guusu Naijiria papaa julọ nilẹ Igbo ati Yoruba ti n da ilu ru.
Bakan naa ni wọn gba ẹmi awọn alaiṣẹ ti wọn si tun ṣe akoba fun ọrọ aje orilẹede Naijiria.
Wọn o ṣetan lati jiroro pẹlu ijọba lori ohun to n dun wọ, nitori naa, wọn o yatọ si Boko Haram ati ẹgbẹ agbesunmọmi ISWAP.
Ko si ohun to jọọ pe Gbajabiamila darukọ ẹgbẹ kankan ninu ọrọ rẹ.
Ohun to sọ naa ni pe awọn ọdaran kan n fi ijijagbara boju lati ṣe iṣẹ ibi.
Gbajabiamila ko tabuku ijijagbara, bẹẹ ni ko si sọ pe awọn to n jija gbara ko yatọ si Boko Haram,'' Lasisi lo sọ bẹẹ.
- Eèmọ̀ wọ̀lú, ẹni tó ń ta ọtí àti ògógóró gún Oníbárà rẹ̀ pa ní Osun!
- Àwa ọmọ Iyabo Oko ló dá owó gọbọi fi gbé ìyá wa lọ sí India fún ìtọjú- Ewa, ọmọ Iyabo Oko
- Wo ọ̀nà méje tí o lè fi dáàbò bò ọmọ rẹ níbàyìí tí iléẹ̀kọ́ ti bẹ̀rẹ̀ padà
- Èmi tí wọ́n kọ́kọ́ pé ọkọ Bimbo kú gàn an ti di jálajála lórí ìròyìn burúkú náà- Jaye Kuti, ọ̀rẹ́ Bimbo Oshin
- Lóòtọ́ ni ìyá yìí bímọ méjì fún ọmọ rẹ̀ tó ń bá sùn, ohun tí a ṣe síi rèé - Àjọ NSCDC Kwara
- Atọ́kùn egúngún, ọmọ rẹ̀ àti èèyàn méjì dèrò àtìmọ́lè lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn ní mọ́ṣálááṣí
















