Fani Kayode defects to APC: Sheikh Gumi ní Judasi ìran Yorùbá ni Fani-Kayode

Femi Fani-Kayode ati Sheikh Ahmad Gumi

Oríṣun àwòrán, Instagram/Real FFK

Ọpọ eeyan papaa julọ lagbo oṣelu lo n ti n bẹnu ẹtẹ lu eekan oṣelu, Oloye Femi Fani-Kayode lori bi o ti fi ẹgbẹ oṣelu PDP lọ darapọ mọ APC ni Ọjọbọ.

Koda awọn onimọ nipa ẹsin gan an ko gbẹyin ninu awọn to koro oju si igbesẹ Fani-Kayode.

Ọkan lara awọn eeyan bẹẹ ni onimọ nipa ẹsin musulumi, Sheikh Ahmad Abubakar Gumi.

Gumi ni Judasi iran Oduduwa ni Fani-Kayode pẹlu igbesẹ rẹ to mu fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọ APC.

Aarẹ Muhammadu Buhari fun ra rẹ lo tẹwọ gba Fani-kayode nile iṣẹ ijọba niluu Abuja ni Ọjọbọ.

Àkọlé fídíò, Femi Falana: Mẹ̀kúnnù gbọ́dọ̀ ṣetán láti gba ẹ̀tọ́ wọn, ìjọba ti kùnà lórí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn

Sheikh Gumi ṣalaye pe Fani-Kayode ko ọrọ to sọ lọdun 2018 jẹ lẹyin to sọ nigba naa pe o san ki oun ku ju ki oun darapọ mọ ẹgbẹ APC tabi tẹ fun Buhari lọ.

Àkọlé fídíò, Suicide Prevention: ìwọ́de yìí wáyé láti gbógun ti pípa ara ẹni

Gumi ni oun ko ka ọrọ Fani-Kayode kun mọ tipẹ tori oun mọ pe ọdalẹ eeyan ni.

Gumi fọrọ yii lede loju opo Facebook rẹ lẹyin ti Fani-Kayode darapọ mọ APC tan l'Abuja.

Ẹ̀mí Ọlọ́run ló darí mi láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Femi Fani-Kayode

Minisita eto irina ofurufu tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Femi Fani-Kayode ti pada darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu to n jọba lọwọlọwọ, All Progressives Congress.

Àkọlé fídíò, Oloye Peter Fatomilola: Ọjọ̀gbọ́n olùkọ́ni ni Jesu àti Orunmila jẹ́, àwòkọ́ṣe sí rere si n

Alaga igbimọ majẹobajẹ ẹgbẹ APC ati gomina ipinlẹ Yobe, Mail Mala Buni lo faa le aarẹ Buhari lọwọ l'Ọjọ Isegun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kẹsa nile aarẹ l'Abuja.

Ikede naa n jade lẹyin oṣu bii melo kan to sabẹwo ati ipade pẹlu awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC kan.

Aarẹ́ Buhari ati Femi FAni-Kayode

Oríṣun àwòrán, Tolu Ogunlesi

"Lonii nile ijọba ni Avuja, eeyan kan wa darapọ mọ ẹgb oṣelu APC. Aarẹ to jẹ ololufẹ gbogbogbo si ti tẹwọ gbaa tọwọ-tẹsẹ. Nitoripe, bi Buhari ṣe ri lẹ ri yẹn". Eyi ni oluranlọwọ aarẹ, Tolu Ogunlesi fi sita.

Ẹwẹ, oloye ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party tẹlẹ yii sọ pe "ẹmi Ọlọrun" lo dari oun lati ṣepinnu lilọ darapọ mọ ẹgbẹ to wa lori alefa.

Minisita tẹlẹ yii ni oun yoo ṣeranwọ lati kọ orilẹede Naijiria.

Ṣaalu nigba kan sẹyin ni FFK gẹgẹ bi inagijẹ́ rẹ bu ẹnu atẹ lu iroyin to fo kiri pe o ti darapọ mọ APC lẹyin ti aworan to ya pẹlu awọn gomina APC bọ sori ayelujara.

Àkọlé fídíò, Abiodun Duro Ladiipo, Moremi: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà ṣùgbọ́n mo kọ̀ láti 'remarry'

Wo àwọn ọ̀rọ̀ to gbankọgbì tí Femi Fani-Kayode ti sọ syin nípa APC

Ki Ọgbẹni Fani-Kayode to lọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC, o jẹ gbajumọ alatako si ijọba ati ẹgbẹ oṣelu APC.

Ẹ wo lara awọn oko ọrọ to ti sọ nipa ẹgbẹ oṣelu naa tẹ́lẹ́:

Lakọkọ o ni irọ nla gbaa ni pe wọn ni oun darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC to si ni o san ki oun ku ju ki oun darapọ mọ awọn oloorun lọ.

Ọrọ FFK

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Femi Fani Kayode tun pe APC ni mujẹ-mujẹ, ẹni ègún, olubaṣe Boko Haram, Fulani Daradaran, apaayan lọwọọwọ, a pa iran rẹ, onija ẹsin, ololufẹ maalu, ole, atu ilu ka ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu aduru ọrọ to sọ.

Ọrọ FFK

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Báwo làwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe fèsì?

Ọpọlọpọ ọmọ Naijiria lo n fi ero ọkan wọn han lori ayelujara nipa bi FFK ṣe darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.

Bi o ṣe n ya awọn kan lẹnu pe ki lo sun un de 'bẹ gan lati darapọ mọ ẹgbẹ ti ẹkẹ eebu rẹ kii ṣi lara wọn, lawọn mii n beere pe talo kan ti yoo tun kuro ni ẹgbẹ alatako, PDP.

Esi ọmọ Naijiria si FFK

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Esi ọmọ Naijiria si FFK

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Esi ọmọ Naijiria si FFK

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Esi ọmọ Naijiria si FFK

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Esi ọmọ Naijiria si FFK

Oríṣun àwòrán, Screenshot