Abiodun Duro Ladipo: Ǹ kò pé '40' ti Bàbá fi papòdà, kò rọrùn láti jẹ́ opó lọ́mọdé àmọ́ mo kọ̀ láti 'remarry’
Odu ni orukọ Duro Ladipo nilẹ Yoruba ati lagbo ere tiata Yoruba, ti kii si se aimọ fun oloko.
Duro Ladipọ ti ọpọ eeyan tun n pe ni Sango jẹ gbajumọ osere tiata nigba aye rẹ, amọ to papoda lọjọ Kọkanla osu kẹta ọdun 1978.
Aya rẹ, ti oun naa jẹ akikanju osere tiata pẹlu ọkọ rẹ, Abiodun Duro-Ladipo ti ọpọ eeyan mọ si Moremi ti wa sọrọ nipa ifẹ nla to wa laarin oun ati ọkọ rẹ.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Moremi salaye bi oun se mọ oloogbe naa, bi ọrọ ifẹ wọn se larinrin to ati idi ti oun se gba lati fẹ akọni osere tiata naa.
Bakan naa lo sọ idi ti ko fi gba ọkunrin kankan laaye tabi fẹ ọkọ miran lẹyin to padanu ọkọ rẹ lai ti pe ẹni ogoji ọdun.
Abiodun Duro-Ladipo wa fidi rẹ mulẹ pe lati ọdun 1978 ti Duro ti papoda, ọpọ eeyan si lo n kofiri rẹ ninu ile awọn eyi to fihan pe ko kuro ninu ile naa.
Iya Duro Ladiipo wa gba awọn ọdọbinrin ni imọran pe ki wọn pa ara wọn mọ.
O ni ko rọrun lati jẹ opo rara amọ o yẹ ki awọn obinrin lọ ni suuru pupọ, ki wọn le jere ọkọ
Iya Moremi tun gba awọn obinrin ni imọran, paapaa awọn ọdọ, pe ki wọn dẹkun lati maa fi ohun ti wọn ko ni jẹ run imu wo rara.