Iyabo Oko ti gba ìtọ́jú ní Uk àti India nígbà tó kọ́kọ́ dùbúlẹ̀ àìsàn

Oríṣun àwòrán, Iyabo_oko
Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Kudirat Odukanmi, ti ọpọ mọ si Iyabo Oko ti dubulẹ aisan.
Ọkan lara awọn oṣere ẹgbẹ rẹ, to tun jẹ oloju aanu, Foluke Daramola lo kede ọrọ naa loju opo Instagram rẹ.
Ṣugbọn ki Foluke to fi ikede naa sita nipa aisan Iyabo Oko yii, agba oṣere naa ti n ṣaisan tẹlẹ lati nkan bii ọdun marun un sẹyin.
- 'Màmá mi, Iyabo Oko ti ní "Left Stroke" ní fọ́tò wọ́n ṣe rí bẹ́yẹn o àmọ́...'
- Ẹ dákun ẹ ran Iyabo Oko lọ́wọ́, ìyá ti ń ṣàárẹ̀ láti ọdún márùn ún sẹ́yìn, o ti kọjá agbára wa- Foluke Daramola Salako
- Ikú dóró! Dudu Heritage, olówó orí Bimbo Oshin ti jáde láyé
- Ọwọ́ ti tẹ ọlọ́pàá tó yìnbọn pa ọmọ ọdún 18 nílùú Eko
- Okòòwò márùn ún tí o lè bẹ̀rẹ̀ nínú ilé rẹ̀
- Ìyàwó Wòlíì TB Joshua di olórí ìjọ Synagogue
- Ẹgbẹ́ àwọn Oníbúrẹ́dì parí ìyanṣẹ́lódì niye owó búrẹ́dì bá lọ sókè!
- 'Jíjẹ ẹran Màálù ti d'èèwọ̀ nílùú wá torí Fulani ṣe...'
Ọdun 2016 ni oṣere ọhun kọkọ ṣaisan.
Gẹgẹ bii ileeṣẹ iroyin City People lọdun naa lọhun ṣe jabọ, nigba to ku oṣu kan ki wọn fun oṣere naa ni ami ẹyẹ gẹgẹ bii oṣere to dantọ ati fun igbiyanju rẹ nidi iṣẹ tiata Yoruba lo dubulẹ aisan.

Oríṣun àwòrán, iyabo_oko
City People ni "A gbiyanju titi lati pe aago ilewọ rẹ ṣugbọn ko lọ, lẹyin oṣu diẹ si asiko naa ni a gbọ pe o n ṣaisan, to si lọ gba itọju nile iwosan ti wọn pe ni 68, eyii to wa ninu baraki awọn ologun ni Yaba, niluu Eko."
Lẹyin naa ni iroyin sọ pe akọbi ọmọ rẹ gbe lọ silẹ Gẹẹsi, ṣugbọn o tun gbe kuro nibẹ lọ si orilẹ-edd India fun itọju to peye.
Ọdun kan lẹyin to lọ gba itọju ni India ni Iyabo Oko pada wale si Naijiria lọdun 2017, ti ara rẹ si da.
Ẹwẹ, lẹyin aisan ọhun atawọn irinajo fun itọju ni Iyabo Oko ru gidi, ṣuigbọn o bẹrẹ si n pada bọ sipo diẹ diẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin City People lọdun 2017, agba oṣere naa ni "Mo dupe lọwọ Ọlọrun to da ẹmi mi si titi di akoo yii, Eṣu gbogun lori ilera mi ṣugbọn Eledua da ẹmi mi si."
Lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2017, Iyabo Oko sọrọ loju opo Instagram rẹ pe irọ ni iroyin ẹlẹjẹ ti awọn eeyan ka gbe kiri pe oun ti jade laye.
O ni lootọ ni oun ṣaisan ṣugbọn ara oun ti mokun, bo tilẹ jẹ pe oun ti ru.
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ lo gbagbọ pe alaafia lo wa lati ọdun naa wa titi di igba ti Foluke Daramola kede pe o tun ti dubulẹ aisan lọjọ kejila, oṣu Kẹsan an ọdun 2021 yii.
Adura wa nileeṣẹ BBC Yoruba ni pe ki Ọlọrun lọra ẹmi agba oṣere naa, ko si tun fun ni alaafia.
- Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Odunlade Adekola nídìí iṣẹ́ tíàtà sọ̀rọ̀ sókè lórí ẹ̀sùn pé ó ń bá àwọn lòpọ̀
- Ìwádìí ti tú àṣírí àwọn tó yìnbọn sí olùwọ́de EndSARS ní Tollgate l'Eko
- "Kò sí ìdáríjí fún àwọn jàndùkú mọ́ báyìí, a óò bẹ̀rẹ̀ sí ń ran wọn lọ sí ọ̀dọ̀ Eledumare"
- Ọ̀bẹ ti bá ọ̀gá DPO tó sọ ìbọn ọlọ́pàá nu lẹ́yìn tó gbé obìnrin sùn sí ọ́fíìsì rẹ̀ nídí














